O ga o! Aṣe awọn ajinigbe ti yinbọn pa pasitọ ijọ Ridiimu ti wọn ji gbe lọna Eruwa

Ọlawale Ajao, Ibadan
Niṣe lẹkun n pe ẹkun ran niṣẹ ni itẹ oku to wa ni Mowo, ni Badagry, nipinlẹ Eko, nigba ti wọn sinku Oluṣọ-agutan Olugbenga Adedọlapọ Ọlawore, ẹni ti awọn ajinigbe yinbọn pa lọsẹ to lọ lọhun-un.

Pasitọ Ọlawore, to jẹ alakooso ṣọọṣi ti wọn n pe ni Heavens Gate Parish, Redeemed Christian Church of God, iyẹn, ẹka ijọ Ridiimu, to wa lọna Agbara si Lusada, nipinlẹ Ogun, ni wọn ji gbe pẹlu awọn ero mẹtala yooku ti wọn jọ wa ninu bọọsi kan naa, ti awọn ọbayejẹ eeyan ọhun si beere fun miliọnu mẹwaa Naira (N10m) ki wọn too le tu u silẹ nigbekun.

Lọjọ kẹta iṣẹlẹ yii ni Kọmiṣanna feto iroyin ninu ijọba Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, Ọmọọba Dọtun Oyelade, kede pe ojiṣẹ Ọlọrun naa ti jade nibuba awọn ajinigbe.

Ṣugbọn nigba ti awọn ẹbi, ololufẹ atawọn ọmọ ijọ Ridiimu lapapọ n foju sọna lati foju kan ẹni wọn ti wọn gbọ pe ori ti ko yọ lọwọ iku ọhun, ṣugbọn ti wọn ko gburoo ọkunrin naa, lawọn agbaagba ijọ bẹrẹ si i gbọ lọkọọkan pe pasitọ naa ko si laye mọ, o wa lara awọn ti awọn ajinigbe naa yinbọn pa.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, loootọ lori ko awọn bii meji kan yọ nigbekun awọn olubi ẹda naa. Ṣugbọn niṣe lawọn ẹruuku ọhun binu yinbọn pa awọn yooku, ti Pasitọ Ọlawore ti wọn n sọ yii ṣi wa ninu awọn ti wọn ran lọ sọrun apapandodo.

Ninu iwaasu to ṣe ko too di pe wọn sinku pasitọ naa, Pasitọ G. Aribisala, sọ pe, “Lọjọ kan la maa foju rinju pẹlu arakunrin wa ninu Ọlọrun, nitori pe gbogbo wa naa la maa ku, ta a o si jẹjọ lori ohun gbogbo ta a ba gbele aye ṣe.

“Ọlọrun ko fi ọjọ ori to iku, gbogbo wa la maa faye silẹ nigba ti asiko ti Ọlọrun kọ mọ onikaluku ba to. Ṣugbọn a dupẹ pe arakunrin wa gbe igbe aye to nitumọ, wọn lo gbogbo aye wọn fun Ọlọrun”.

Oniwaasu yii rọ awọn to kopa nibi eto isinku naa lati lo igbesi aye wọn fun Ọlọrun bii ti pasitọ to doloogbe yii. Oniwaasu yii figbagbọ ẹ han pe awọn to pa pasitọ naa ko le mu un jẹ gbe, gbogbo wọn ni wọn yoo jiya ẹṣẹ wọn lọjọ idajọ niwaju Ọlọrun.

Nigba to n gbe oku ọga ẹ sinu saaree, igbakeji pasitọ ẹka ijọ Ridiimu ẹkun kẹtalelaaadọrin (Privovince 73), nipinlẹ Eko, nibi ti Oloogbe Ọlawore n dari nigba to wa laye, Pasitọ Niyi Ọlaniran, gba gbogbo eeyan niyanju lati ronupiwada, ki wọn si jawọ ninu iwa ẹṣẹ, nitori lojiji ni iku ti yoo pa onikaluku yoo de ba a.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbe e jade ṣaaju, laipẹ yii ni pasitọ ti wọn gbẹmi ẹ yii padanu iya ẹ, to n jẹ Diakoni Deborah Ọlawore.

O wa lara awọn to fi eto itẹ ẹyẹ oku iya ẹ si ọjọ Jimọ, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Kẹrin to kọja yii, ti wọn si fi aṣekagba ayẹyẹ isinku ọhun si ọjọ Jimọ to tẹlẹ e, ti i ṣe ọjọ kẹta, oṣu Karun-un ta a wa yii, laimọ pe gbogbo eto ọhun ko ni i ba oun paapaa laye.

Ara eto ti yoo mu ki ayẹyẹ isinku iya naa larinrin lo n ba lọ si ilu Ipapo, lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ. Ṣugbọn bo ṣe n pada s’Ekoo lẹyin to ti pari eto isinku iya ẹ lawọn janduku agbebọn yọ si oun atawọn mẹtala yooku ninu ọkọ bọọsi elero mẹrinla to wọ, ti wọn si fibọn dari wọn lọ sinu aginju ninu igbo.

Idunnu ti kọkọ ṣubu lu ayọ nigba ti Ọmọọba Oyelade ti i ṣe kọmiṣanna feto iroyin Makinde, kede pe wọn ti yọ pasitọ naa nibuba awọn ajinigbe, ṣugbọn idunnu ọhun ko lọ titi nigba ti ododo to wa nidii ọrọ yii foju han pe awọn ẹruuku ti pa oluṣọagutan naa, wọn si jọwọ oku ẹ sibi ti awọn eeyan rẹ ti le ri i.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ṣe lawọn eeyan n sunkun àsunwọrùn nibi itẹ ẹyẹ ati eto isinku ọkunrin ẹni ọdun metalelaaadọta (53) naa.

 

Ọpọ eeyan lo royin rẹ gẹgẹ bii ọmọluabi.

Leave a Reply