O ga o! Aṣọ ni Iya Aina lọọ ka nile keji, ko too de, wọn ti ji ọmọ ẹ lọ n’lbadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bo tilẹ jẹ pe ikẹ Ọlọrun ti gbogbo aye maa n beerr fun ni ojo jẹ, sibẹ, ijanba ti ojo to rọ n’Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii mu ba awọn idile kan pẹlu bi obinrin kan ti wọn pe ni Iya Aina ṣe padanu ọmọ rẹ lasiko ti ojo naa n rọ lọwọ, ti agbara ojo ọhun si gbe odidi eeyan meji lọ.

Ọlọkada kan pẹlu ọmọdekunrin kan to gbe ni wọn tẹ ri soju odo kan ti wọn n pe ni Orogun, n’Ibadan, nigba ti awọn mejeeji ṣubu sinu odo ọhun to ru ja oju titi latari alagbalugbu oni tó ya lulẹ lati oju sanmọ lalẹ ọjọ naa.

Wọn ni odo to kun akunya si oju titi yii lo gbe ọkada ti wọn gun ṣubu, bo si tilẹ jẹ pe wọn ṣakitiyan lati jade kuro ninu alagbalugbu oni naa, sibẹ pabo ni gbogbo ilakaka wọn ja si, niṣe lomi naa papa gbe wọn lọ. Ẹnikẹni ko si ti i gburoo wọn titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Ẹẹmeji ọtọọtọ lojo yii rọ lawọn agbegbe bii UI, Sango, Apẹtẹ, Ọlọmọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ọkan rọ laarin aago meje si aago mẹjọ alẹ nigba ti ekeji bẹrẹ ni nnkan bii aago mọkanla, to da ni nnkan bii aago kan oru.

Ojo to kọkọ rọ lo gbe ọlọkada pẹlu ọmọdekunrin to gbe lẹyin lọ ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ naa.

Anfanai ojo yii kan naa lawọn gbọmọgbọmọ lo lati ji ọmọ kan ti ko ju ọmọọdun kan lọ gbe laduugbo ti wọn n pe ni Oke-Oko, nitosi Ọlọmọ, nigboro ilu Ibadan.

Olugbe adugbo ọhun to fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ fakọroyin wa ṣalaye pe “ẹyinkule nIya Aina yẹn wa pẹlu ọmọ rẹ yẹn. Nigba ti ojo bẹrẹ lojiji lobinrin yẹn sare lọọ ka aṣọ to sa si ile keji ọdọ wọn. Ṣugbọn nigba ti yoo fi pada de, ko ba ọmọ nibi to gbe e si mọ.

“O ni lati jẹ pe ẹni to gbe ọmọ yẹn ti n ṣọ Iya Aina tẹlẹ. Koda, o le jẹ araadugbo wa gan-an.”

Ọpọlọpọ paanu lawọn ojo naa ṣi danu, to ṣi sọ awọn ile onile di ahoro. Bẹẹ lo bi awọn ile kan ti wọn n kọ lọwọ wo lulẹ, to si sọ awọn ile ọhun di alapa.

Leave a Reply