O ga o: terela Dangote tun g’ori ọlọkada l’Agọ-Iwoye, o pa a patapata

Laaarọ yii ni. Ere buruku ni wọn ni mọto terela Dangote naa n ba bọ, o n bọ lati inu Agọ-Iwoye, o fẹẹ kọri sọna Ijẹbu-Ode ni. Afi bo ṣe de ibi ikorita abajade-niluu ti ọwọ mọto gbodi mọ ọn lọwọ. N lo ba gori ọlọkada kan to n lọ jẹjẹ tirẹ, bẹẹ lo pa a danu, to si ṣe awọn mẹta mi-in leṣe. N lawọn araalu to wa nitosi ba binu, wọn dana sun terela naa, wọn si mura lati lu dẹrẹba to wa a pa.

“O fẹrẹ jẹ pe nnkan mi-in wa lara awọn dẹrẹba ti wọn n wa mọto Dangote kiri, awọn ti wọn fi n ko simẹnti ati awọn nnkan mi-in, iwakuwa wọn ti pọ ju, ere asapajude ni wọn maa n sa bii pe ko si ohun ti ẹnikẹni le fi wọn ṣe. Ohun to si ṣẹle ni Agọ-Iwoye laaarọ yii niyẹn.” Bẹẹ lẹni kan ti ọọ yii sọju rẹ so f’Alaroye.

Apala ko jiya to ọkunrin to wa terela yii nigba ti awọn araalu ki i mọlẹ nibi to ti fẹẹ maa sa lọ, wọn ko kumọ bo yẹyẹ, wọn n fẹẹ yanju ẹ lẹẹkan koun naa maa tẹ le ọlọkada lọ. Ṣugbọn awọn agbofinro ti wọn wa nitosi ko jẹ, wọn gba a lọwọ wọn, wọn si mu un lọ si agọ ọlọpa Igbẹba ni Ijẹbu-Ode.

Alukoro ajọ to n dari ọkọ loju popo lagbegbe naa, Babatunde Akinbiyi, ni ọrọ naa ko ba ti buru to bẹẹ bi ki i baa ṣe ere asaju ti ọkunrin to wa terela naa n sa. Igba to sare de ikorita ọna Ibadan, to ni ki oun yiwọ jade s’ọna Ijẹbu-Ode ni mọto gba ibomi-in mọ ọn lọwọ, to fi di pe o lọọ pa ẹni ẹlẹni to n gun ọkada Bajaaj rẹ lọ.

Wọn ti gbe oku ọkunrin naa lọ si mọṣuari to wa ninu ọsibitu Femtop n’Ijẹbu-ode nibẹ, ti awọn ti wọn fara pa si n gba itọju. Ma jẹ ka rin lọjọ ti ebi yoo pa ọna Ọlọrun; ka ma rin arinfẹsẹsun; ki oloriburuku ma si ko tirẹ ba wa.

Leave a Reply