Adewale Adeoye
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede wa, ẹka ti ‘231 Battalion’, to wa niluu Biu, nipinlẹ Borno, ti kede pe awọn ti gbaṣọ lọrun ṣọja kan, Kọpura Abdullah Ismail, ti wọn fẹsun iwa palapala kan. Wọn ni o ba iyawo ọrẹ rẹ sun.
ALAROYE gbọ pe inu baraaki awọn ṣọja, nibi ti Kọpura Abdullah n gbẹ pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ gbogbo lo ti dẹnu ifẹ kọ iyawo ọrẹ rẹ, to si pada ba a sun, eyi tawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii ni ki i ṣ’ohun to daa rara pe ki ṣọja maa fẹ iyawo ara wọn ninu ọgba ibi ti wọn n gbe.
Gbara ti awo ọrọ ọhun lu sita ni wọn ti bẹrẹ si i ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ẹri si fi han gbangba pe ootọ ni ẹsun tawọn ara baraaki ti wọn n gbe fi kan Kọpura Abdullah yii.
Lara iwadii ti wọn ṣe nipa esun naa ni wọn ti tun ri ẹri mi-in pe igba akọkọ kọ ree ti yoo ba obinrin naa laṣepọ, wọ ni ọjọ ti pẹ ti Kọpura Abdullah ti maa n lọ kaakiri inu baraaki naa, ta a si maa yan awọn iyawo ile gbogbo tọkọ wọn jẹ ṣọja bii tiẹ lọrẹẹ ikọkọ, ko too di pe wọn gba a mu, ti wọn si fi i jofin bayii.
Wọn ni idajọ rẹ maa jẹ ẹkọ nla fawọn ọbayejẹ kọọkan ti wọn n hu iru iwa palapala ti Kọpura Abdullah n hu yii.