O ku diẹ ki ọga ọlọpaa yii fẹyinti, ko bẹrẹ iṣẹ lọọya, lawọn janduku ọlọkada pa a danu

Faith Adebọla

Bi wọn ba pe iku ọga ọlọpaa Kazeem Abonde yii ni ‘iku-bọla-jẹ,’ o ba a mu wẹku, tori ọpọ ohun ribiribi ti ọkunrin naa n gbero lati ṣe, ati ipo pataki to wa ni iku airotẹlẹ yii sọ di ala ti aja la, ti wọn ni inu aja lo n gbe.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹsan-an yii, ko le parẹ bọrọ lọkan awọn mọlẹbi Oloogbe Abọnde, ọjọ naa ni agbofinro to ti wa nipo ọga agba, Chief Superintendent of Police, ti wọn n pe ni CSP, jade laaye, ṣugbọn to jẹ mọṣuari lo pari irinajo ọjọ naa si.

Awọn janduku ọlọkada kan tinu n bi ni wọn ni wọn gbinaya lọjọ naa, ti wọn bẹrẹ si i ṣakọlu si ikọ amuṣẹya ti oloogbe yii ko sodi lati mu awọn ọlọkada ti wọn lufin irinna ni gareeji ọlọkada to wa nitosi Eleganza ati adugbo Canoe, atawọn janduku ti wọn fi Ajao Estate ati agbegbe rẹ ṣe ibuba wọn, lọjọ naa. Inu akọlu ọhun ni wọn pa ọga ọlọpaa yii si, ipa oro si ni wọn pa a, wọn fi okuta, igi ati ibọn fọ ọ lori ni, wọn si fi i silẹ ninu agbara ẹjẹ rẹ, wọn sa lọ.

Ba a ṣe gbọ, oṣu mẹjọ pere lo ku ti ọga ọlọpaa yii iba fẹyinti lẹnu iṣẹ ọlọpaa. Awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn mọ ọn daadaa sọ pe akikanju ẹda ni, tori bo ṣe n ṣiṣẹ ọlọpaa lọkunrin naa n kawe ofin labẹnu, o si ti gboye jade gẹgẹ bii Amofin, o tun ti lọ sileewe tawọn lọọya ti n kẹkọọ, o si yege. Ọpọ igba lo ti ṣoju ileeṣẹ ọlọpaa nile-ẹjọ, ọkan ninu awọn fọto ti wọn fi lede lẹyin iku rẹ safihan oloogbe naa nibi to ti wọṣọ agbejọro, to si de wiigi wọn niwaju adajọ.

Iṣẹ lọọya yii la gbọ pe ọkunrin naa n gbero lati jokoo ti to ba fẹyinti lọdun to n bọ, wọn ni o ti ṣe ọfiisi ti yoo ti maa ṣiṣẹ, ti yoo si maa da awọn kọsitọma rẹ lohun, ṣugbọn kokoro buruku ko jẹ ka gbadun obi to gbo lọrọ da bayii pẹlu iku ọsan-gangan to mu un lọ yii.

Bakan naa ni wọn ni Kazeem ti n palẹmọ fun ayẹyẹ ifẹyinti rẹ, wọn lọpọ igba lo n sọrọ nipa awọn eto ati imurasilẹ toun fẹẹ ṣe, tori bo ṣe n bọ aṣọ kaki ọlọpaa lọrun ni yoo maa wọ wiigi lọọya, ọpọ awọn nnkan meremere ti yoo fi ṣ’ẹṣọ sọfiisi tuntun naa lo ti n ra pamọ wẹrẹwẹrẹ.

Ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ Abonde lẹka iṣẹ ọlọpaa Eko sọ pe adanu nla ni iku Abonde jẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa Eko ati Naijiria, tori ọjafafa agbofinro to fi ọmọluabi kun iṣẹ rẹ ni ọkunrin naa i ṣe.

Wọn niwa ọmọluabi rẹ yii wa lara ohun to ṣee ṣe ko ṣokunfa iku oro to ka a mọ yii, tori lasiko ti oloogbe naa n fọgbọn parọwa sawọn janduku naa, to si n gbiyanju lati bomi tutu si wọn lọkan lawọn ẹhanna ẹda to wa laarin wọn yinbọn, ti wọn si bẹrẹ si i ṣe e leṣe titi tẹmii fi bọ lẹnu rẹ.

Leave a Reply