O ku oṣu kan ki Wuyi ṣegbeyawo lo ku sori aṣẹwo l’Ekoo

Ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Wuyi Jackson to n wa ọkọ epo, ti gba ibi to gba wa sate lọ sọrun pẹlu bo ṣe ku sori aṣẹwo lẹyin raundi meji to ṣe.

Ohun to ba ni ninu jẹ ninu ọrọ ọmọkùnrin to n ṣiṣẹ nileeṣẹ epo kan ni Ajah, l’Ekoo, ni pe oṣu to n bọ lo yẹ ko ṣegbeyawo.

ALAROYE gbọ pe Dẹpo to wa ni Ijegun, ni Satellite Town, lọmọkunrin naa ti waa loodu tanka rẹ pẹlu epo bẹntiroolu. Eyi ni wọn n ṣe lọwọ to fi gba otẹẹli kan to wa laduugbo Oluti lọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ lati lọọ ṣe faaji. Lẹyin to ta nnkan sara tan lo dunaa-dura pẹlu obinrin aṣẹwo kan ti wọn porukọ ẹ ni Faith Ifeanyi.

Lẹyin ti ọrọ wọ laarin wọn lo mu un wọle, ko pẹ ti wọn wọle ni ọrọ yiwọ, bo ṣe di pe Wuyi daku rangbandan lẹyin raundi meji to ṣe lori aṣẹwo nìyẹn. Ki wọn si too mọ ohun to ṣẹlẹ, ọmọkunrin naa ti kọja sodikeji.

Ọmọbinrin aṣẹwo naa ṣalaye pe ẹgbẹrun mẹwaa loun ni oun fẹẹ gba lọwọ rẹ ko too na an si meje. Bi ina ṣe wọ lọkunrin naa ti kọkọ wọle kanlẹ lara oun. Lẹyin raundi akọkọ ni Gift ni awọn sun lọ.

Ni nnkan bii aago meji aabọ oru ni Wuyi tun ji oun pe kawọn tun waa ṣe ‘kinni’. Aṣẹwo ni nibi to ti n ṣe ẹlẹẹkejì lọwọ lọmọkunrin to yẹ ko ṣegbeyawo ninu oṣu kẹsan-an ta a fẹẹ mu yii ti bẹrẹ si i mi tupetupe.

Gift ni oju ẹsẹ loun pariwo pe kawọn to wa nitosi gba oun, lawọn ba sare gbe e lọ si ọsibitu to wa nitosi. Ibẹ ni wọn ti ni kawọn maa gbe e lọ si ọsibitu ijọba to wa ni Yaba. Ko si duro gba aajo rara to fi dagbere faye. Ọmọbìnrin yii ni bi awọn ṣe gbe e debẹ ni dokita sọ fun awọn pe oku lawọn gbe wa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Bala Elkena, sọ pe Gift ṣi wa latimọle awọn.

 

Leave a Reply