O ku ọjọ diẹ ki ọmọ mi ṣọjọọbi lawọn apaniṣowo pa a mọ mi lọwọ- Baba akẹkọọ MAPOLY

Ọlawale Ajao, Ibadan, Gbenga Amos, Ogun

Niṣe lomi le roro loju Alakooso agba ileewe gbogboniṣe Moshood Abiọla Polytechnic (MAPOLY), to wa niluu Abẹokuta, Ọmọwe Ọdẹdeji Adeoye, pẹlu Ọgbẹni Yẹmi Ajibọla, ti i ṣe Alukoro ile-ẹkọ giga naa, atawọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ileewe yii, nigba ti wọn ṣabẹwo si awọn obi akẹkọọ poli ọhun, Odeh Happiness, ti wọn pa lọsẹ to kọja.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lọjọ kẹta ti Hapiness jawe olubori gẹgẹ bii akẹkọọ to rẹwa ju lọ lobinrin nileewe naa lo kagbako iku ojiji yii.

Ohun ta a gbọ ni pe ọrẹ ọmọbinrin yii kan to wa nitosi ileewe Poli Gateway, to wa lagbegbe Ijẹbu, ni Ipẹru Rẹmọ, lo ke si i lati waa kopa ninu fiimu kan ti wọn n ya lọwọ, lati fi ṣe sinima.

Nigba to si jẹ ẹkọ nipa iru nnkan bẹẹ ni akẹkọọ-binrin naa n kọ nileewe rẹ, o mura lati lọ, wọn loun ati ọrẹ rẹ kan ni wọn jọ lọ. Ṣugbọn wọn ko mọ pato ibi ti wọn n lọ, wọn ni niṣe ni wọn n ba onitọhun sọrọ lori aago, nigba ti wọn si fi maa bọọlẹ ninu ọkọ to gbe wọn de agbegbe Iperu, ọlọkada kan lo gbe awọn mejeeji, o loun maa gbe wọn lọ sibi ti wọn yoo ti lọọ ṣiṣẹ ni lokeṣan, ṣugbọn nigba ti ọlọkada naa gbe wọn, niṣe lo ji wọn gbe, alọ la ri, a o ri abọ awọn ọmọ naa. Ọjọ keji ti wọn yoo ri wọn, oku wọn ni wọn ri ninu igbo kan, ami si wa pe wọn ti fipa ba wọn laṣepọ, ki wọn too pa wọn, ti wọn si tun yọ ẹya ara wọn lọ.

ALAROYE de ile awọn ọmọbinrin naa l’Oke Ṣokori, lagbegbe Ita-Ẹkọ, niluu Abẹokuta, bẹẹ la ṣabẹwo sinu ọgba MAPOLY ti ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun (22), naa n lọ, iwọnyi ni ohun ti baba ẹ, igbimọ alaṣẹ ileewe ọhun pẹlu aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ poli naa ba akọroyin wa sọ:

‘‘Eni ọdun mejilelaaadọta (52) ni mi. Oṣiṣẹ ijọba ni mi. Mo jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Benue.

‘‘Ọmọkunrin kan lo pe mi pe oun gba ipe kan lati Iperu.  O ni ẹni yẹn sọ pe oun ri foonu kan lara oku kan ti oun ri lẹgbẹẹ titi lojugbo kan, oun waa pe nọmba ti ọmọbinrin yẹn ba sọrọ gbẹyin lori foonu rẹ. O ni ẹni yẹn sọ pe ṣe oun mọ ẹni to ni foonu yẹn, o ni oun mọ ọn, o waa ni ki oun waa gba foonu yẹn ni Iperu.

‘‘Bẹẹ, a ti n pe nọmba Happiness lati bii ọjọ meji sẹyin ti ko lọ. Laaarọ ọjọ yẹn ti ọmọkunrin yẹn waa ba mi naa ni mo tẹle e lọ si Iperu. Ni Iperu ni wọn ti sọ pe ka tun maa bọ ni agọ ọlọpaa Ode-Rẹmọ. Nigba ta a de agọ ọlọpaa ni DPO sọ fun wa pe oun loun pe ọmọkunrin to waa mu mi nile yẹn. DPO beere lọwọ ọmọkunrin yẹn pe bawo lo ṣe jẹ si ọmọ mi, o lọrẹẹ lawọn. Ibẹ ni DPO ti ṣẹṣẹ waa ṣalaye ohun to sẹlẹ fun mi. Ṣapade, ni Ipẹru, lọmọ mi sọ pe oun n lọ. O sọ fun mi pe oun fẹẹ lọọ kopa ninu ere kan. Mo si gba a laaye lati lọ.

‘‘Ohun to ku bayii ni bi mo ṣe maa gba oku ọmọ mi jade ni mọṣuari, ki n si lọọ sin in siluu wa. Iṣoro ti mo ni bayii niyẹn nitori iṣẹlẹ yii ba wa lojiji, a ko lowo lọwọ bayii, worobo niyawo mi n ta niwaju ile. Happiness la bi ṣikeji ninu ọmọ mẹrin ta a bi. Ọmọ to lọjọọwaju ni Happiness. O mọ keeki i ṣe pupọ.

‘‘Lọjọ to gba ami-ẹyẹ akẹkọọ to rẹwa ju lọ nileewe ẹ, o sọ fun mi. Inu mi dun. Aṣe ode to dagbere fun mi lẹyin igba naa ni mo fi maa ri i gbẹyin. Lọjọ Sannde to lọ lọhun-un, oun lo ṣe keeki tá a jẹ ní ṣọọṣi fún ayẹyẹ ọjọọbi ẹ. Tọsidee lọjọọbi ẹ bọ si, ṣugbọn lati Sannde lo ti ṣe keeki ọjọọbi ẹ silẹ, ta a si jẹ ẹ. Aṣe ọmọ mi ko ni i di ọjọ ọjọọbi ẹ laye.

Leave a Reply