O le jẹ awọn janduku lo wọ aṣọ ṣọja, ti wọn yinbọn paayan ni Lẹkki-Adajọ agba ilẹ wa

Minisita fun eto idajọ nile wa, Abubakar Malami, ti sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn janduku ni wọn ko aṣọ awọn ṣọja wọ, ti wọn si lọọ yinbọn lu awọn ọdọ to n ṣewọde ta ko SARS ni Lẹkki, nipinlẹ Eko, logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lo sọ eleyii di mimọ. O ni iwadii ti n lọ lọwọ lati mọ awọn ti wọn yinbọn lu ati boya wọn tiẹ yinbọn naa rara nibẹ.

Adajọ agba yii ni ki ẹnikẹni ma ti i maa gbe igbekugbee kiri lori iṣẹlẹ naa. O ni o ṣee ṣe ko jẹ awọn ọmọ ita ti wọn waa lọwọ si iwọde naa ti wọn kan fẹẹ fi a wahala silẹ ni wọn ṣiṣẹ buruku naa.

One thought on “O le jẹ awọn janduku lo wọ aṣọ ṣọja, ti wọn yinbọn paayan ni Lẹkki-Adajọ agba ilẹ wa

Leave a Reply