O lewu bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe ko awọn ọdaran sinu igbimọ ti yoo ṣeto igbajọba l’Ọṣun – OSRA

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ kan nipinlẹ Ọṣun, Ọṣun Shall Rise Again (OSRA), ti ke si ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, Usman Akali Baba, lati tete gbe igbesẹ lori eto aabo nipinlẹ Ọṣun ṣaaju ifilọlẹ ijọba tuntun ti yoo waye loṣu Kọkanla, ọdun yii.

OSRA woye pe bi orukọ omọkunrin kan ti awọn ọlọpaa ti kede loṣu diẹ sẹyin pe awọn n wa fun oniruuru iwa ọdaran to ti hu ṣe wa lara awọn igbimọ ti yoo ṣeto gbigba eeku ida iṣakoso fun Sẹnetọ Ademọla Adeleke jẹ nnkan to ti da jinnijinni si ọkan awọn araalu bayii.

Ninu atẹjade kan ti Alaga ati Akọwe ẹgbẹ naa, Saheed Bakare ati Lanre Akẹju, fi sita bi wọn ti ni igbesẹ awọn PDP naa fi han pe ewu n bẹ loko longẹ ṣaaju ati lasiko ijọba tuntun to n bọ l’Ọṣun.

Atẹjade naa sọ pe “O ya wa lẹnu bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fi orukọ ọdaran ti awọn ọlọpaa ti kede pe awọn n wa, Ajagungbade Ọlalekan, sinu igbimọ ti yoo ṣe ifilọlẹ ijọba tuntun fun Sẹnetọ Ademọla Adeleke.

“Bi wọn ṣe fi orukọ Ọlalekan ti gbogbo eeyan mọ si Emir sinu igbimọ naa tumọ si pe ẹgbẹ PDP ati Adeleke n ko awọn janduku jọ lati dunkooko mọ awọn araalu ati ipaniyan ṣaaju ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla, ọdun yii, o tun tumọ si pe awọn gan-an ni wọn n fi Emir pamọ.

“A ri i bi orukọ rẹ ṣe wa lara awọn igbimọ ti yoo ṣeto aabo fun eto naa gẹgẹ bii ọna lati daabo bo o lọwọ ofin, bẹẹ ni wọn tun fun un lagbara si i lati tẹsiwaju ninu iwa laabi to n hu kaakiri.

“To ba jẹ pe awọn ọlọpaa fẹẹ ṣiṣẹ wọn gẹge bo ṣe wa ninu atẹjade ti wọn gbe jade nipa Emir loṣu Keje, ọdun yii, o yẹ ki wọn ti ranṣẹ si awọn aṣaaju ẹgbẹ PDP ati Adeleke lati waa sọ ohun ti wọn ri ti wọn fi sọ Emir di ọmọ igbimọ ati idi ti wọn fi n gbe e pamọ latigba yii wa.

“A fẹẹ ran ọga agba ọlọpaa leti pe bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ṣe fẹẹ gbiyanju lati fi ọwọ bo ẹjọ ipaniyan to waye niluu Ẹdẹ, eleyii to ni i ṣe pẹlu ọga ikọ alaabo fun gomina tuntun, CSP Isaac Ọmọyẹle ti wọn fẹsun kan pe o pa Abedeen Adekunle ati Kafayat Adekunle, ko too di pe olu ileeṣẹ ọlọpaa l’Abuja da si i.

“O jẹ nnkan itiju, aṣilo agbara, fifaaye gba iwa ọdaran ati ainaani ọrọ eto aabo ipinlẹ Ọṣun pẹlu bi ẹgbẹ PDP ṣe fi orukọ Emir, ẹni ti awọn ọlọpaa sọ pe awọn n wa lori ẹsun ipaniyan, jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun atawọn iwa ọdaran mi-in, sinu igbimọ naa.

“Ipenija nla ni ọrọ yii jẹ fun kọmiṣanna ọlọpaa tuntun to n bọ nipinlẹ Ọṣun, nitori nnkan to lewu ni ki ẹni to jẹ ọdaran maa jokoo pẹlu ẹni ti yoo jẹ olori eto aabo ipinlẹ Ọṣun lati ṣepade papọ. Aabo ẹmi ati dukia awọn araalu ṣe koko”

Amọ ṣa, ẹgbẹ PDP naa fesi, wọn ni Emir ki i ṣe ọdaran, o si ti lọ si ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Oṣogbo pe ki wọn ka awọn ọlọpaa lapa ko lori bi wọn ṣe sọ pe wọn n wa oun, bẹẹ ni adajọ si ti sọ pe ki awọn ọlọpaa tu okun lọrun rẹ.

Leave a Reply