O ma ṣe, awọn agbebọn yinbọn pa oluṣọ-aguntan kan l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Awọn agbebọn kan ti wọn fura si gẹgẹ bii ajinigbe ti yinbọn pa Rẹfurẹndi Johnson Ọladimeji to jẹ alufaa ijọ Solution Baptist Church, to wa niluu Ikẹrẹ-Ekiti.

Ọjọbọ, Tọsidee, niṣẹlẹ ọhun waye loju ọna Igbara-Odo si Ikẹrẹ-Ekiti, lasiko ti oluṣọ-aguntan ọhun n bọ lati ipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn ọjọ keji ti i ṣe Furaidee, lawọn mọlẹbi ẹ too mọ.

Gẹgẹ bi ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ naa ṣe sọ fun ALAROYE, ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ lawọn agbebọn yii da emi oloogbe legbodo, nigba tawọn mọlẹbi ẹ ko si ri i ni wọn bẹrẹ si i waa kaakiri, ki wọn too ba a ninu mọto ẹ ti wọn yinbọn pa a si loju titi.

Lẹyin eyi ni wọn lọọ sọrọ naa fawọn ọlọpaa Igbara-Odo, wọn si gbe oku rẹfurẹndi yii lọ si mọṣuari.

Ninu alaye to ṣe, adari ijọ Baptist nipinlẹ Ekiti, Rẹfurẹndi Adeyinka Aribasoye, fidi ẹ mulẹ pe oloogbe naa lọọ ki iya ẹ niluu Ipetu Ijẹṣa, nipinlẹ Ọṣun ni, nigba to si n bọ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si i.

O ni, ‘Iṣẹlẹ yii jọ ijinigbe to ja si iku. O ṣee ṣe ko jẹ nigba ti wọn da a duro ti ko fẹẹ duro ni wọn yinbọn pa a.

‘Awọn mọlẹbi ẹ bẹrẹ si i wa a nigba ti wọn ko gburoo ẹ, eyi lo jẹ ki wọn maa pe gbogbo awọn to mọ nipa irin-ajo ẹ, ki wọn too pada ri i nibi ti wọn pa a si.’

Lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii, ASP Sunday Abutu to jẹ Alukoro ọlọpaa Ekiti sọ pe oun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn o daju pe awọn yoo wa awọn oniṣẹ laabi ọhun ri tawọn ba gbọ nipa ẹ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lẹyin ọdun mẹta ti tẹnanti tilẹkun ile pa, adajọ ni ki lanlọọdu lọọ ja a n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ilọrin paṣẹ ki …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: