O ma ṣe o, aṣofin ipinlẹ Ondo ku lojiji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe ni ibanujẹ dori awọn eeyan ilu Akurẹ  kodo latari iku ọmọ ileegbimọ aṣofin kan, Adedayọ Ọmọlafẹ, tọpọ eeyan mọ si Expensive, ẹni ti wọn lo deedee ku lojiji ni nnkan bii aago meji oru ọjọ Aiku, Sannde, si ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.

Oloogbe ọhun ni wọn dibo yan lasiko eto idibo gbogbogboo to waye lọdun 2019 lati ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Guusu ati Ariwa Akurẹ nileegbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bakan naa ni wọn tun ti dibo yan an ri gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ Guusu Akurẹ lasiko iṣejọba Oloogbe Oluṣẹgun Agagu.

Aṣofin ọmọ bibi ilu Akurẹ ọhun ni wọn ni ko saisan rara pẹlu bawọn alatilẹyin rẹ kan ṣe fidi rẹ mulẹ pe awọn si jọ ṣere daadaa nigba ti awọn jọ wa papọ lọjọ Aiku, Sannde.

Wọn ni kayeefi nla lo jẹ fawọn lati gbọ iroyin iku rẹ lojiji loru ọjọ naa mọju.

Ọkan-o-jọkan iṣẹ ibanikẹdun lawọn eeyan ti n ran sawọn ẹbi Ọnarebu naa ni kete ti iroyin iku rẹ ti gba ilu kan laaarọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Leave a Reply