Ọlawale Ajao, Ibadan
Aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Ila-Oorun Guusu Ibadan Keji, (Ibadan South East II), Ọnarebu Ademọla Oluṣẹgun Popoọla, ti jade laye.
Alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun 2022 yii, laṣofin naa dakẹ si ileewosan ijọba apapọ, iyẹn University College Hospital (UCH), to wa niluu Ibadan.
Oludamọran feto iroyin fun Ọnarebu Debọ Ogundoyin ti i ṣe olori ileegbimọ aṣofin Ọyọ, Alhaji Oyekunle Oyetunji, lo fidi iroyin yii mulẹ fakọroyin wa n’Ibadan laaarọ Ọjọruu.
Aisan to ni i ṣe pẹlu ẹdọ fooro ni wọn lo ṣe ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46) naa.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, o ti to bii oṣu meji kan ti Ọnarebu Popoọla, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Popson, ti wa nileewosan UCH, ko too di pe aisan ọhun gbẹmi ẹ loru mọju.
Ṣaaju iku ẹ, aṣofin tawọn ololufẹ ẹ mọ si Popson yii, ni alaga igbimọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ.
Awọn eeyan kaakiri ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ si i ranṣẹ ibanikẹdun si idile oloogbe naa ati ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), nitori ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni nigba aye ẹ.