Ọlawale Ajao, Ibadan
Ba a ṣe n wi yii, dokita meji ọtọọtọ laisan iba lasa ti ran lọ sọrun apapandodo.
Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita nipinlẹ Ọyọ, Dokita Ayọtunde Fasunla, lo fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Dokita Fasunla, ẹni to ta ijọba atawọn araalu lolobo pe ajakalẹ arun lasa tun ti rapala wọ ipinlẹ Ọjọ, sọ pe kayeefi lo jẹ foun atawọn dokita ẹgbẹ oun yooku, pe iku awọn dokita mejeeji wọnyi ko ju aarin wakati meji lọ sira wọn.
Ọga awọn dokita yii waa rọ awọn ẹgbẹ ẹ lati maa kiyesara gidigidi nigbakugba ti wọn ba n tọju alaisan yoowu ti wọn ba gbe wa sileewosan wọn, ko ma lọọ di pe wọn yoo lugbadi aisan latara iru alaisan bẹẹ.
O lo oore-ọfẹ atẹjade yii lati pẹtu sawọn mọlẹbi awọn oloogbe ninu pẹlu adura pe ki Ọlọrun tẹ awọn alaisi naa safẹfẹ rere.
Bakan naa lo rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati tete gbe igbesẹ ti yoo fopin si itankalẹ aisan naa lawọn agbegbe to ti n ṣọṣẹ ko too di pe o tan de awọn agbegbe mi-in.