Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oṣun ti bẹrẹ iwadii lori iku to pa Treasure Salakọ, akẹkọọ onipele akọkọ nileewe giga Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ileefẹ.
Inu ile akọku lagbegbe Lagere, niluu naa, la gbọ pe wọn ti ri oku Treasure ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun yii.
Bakan naa ni wọn ba ike majele Snipper, nitosi ibi ti ọmọbinrin naa ku si, eyi to mu ki awọn kan maa sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ṣe lo pa ara rẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iku Treasure.
O ni, “A ti gbe oku rẹ sile igboku-pamọ-si ti OAUTHC, Ileefẹ. Awọn kan n sọ pe o le jẹ pe ṣe ni ọmọ naa pa ara rẹ latari majele ti wọn ba nitosi ibi to ku si.
“Ṣugbọn awa fẹẹ ṣewadii lati le mọ nnkan to fa iku rẹ. Ni ọsibitu, awọn dokita maa ṣe ayẹwo oku, a si maa tu iṣu desalẹ ikoko lori iṣẹlẹ naa.”
Bakan naa ni Alukoro fun Fasiti Ifẹ, Abiọdun Ọlanrewaju, sọ pe ajalu nla ni iku ọmọdebinrin naa, o ni bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe sakani awọn lo ti ṣẹlẹ, sibẹ, ibanujẹ nla lo jẹ.
Ọlanrewaju ṣalaye pe o dun ọga agba fasiti naa, Ọjọgbọn Banirẹ, pupọ pe awọn padanu Treasure si iru igbesẹ ti awọn kan gbagbọ pe ṣe lo kan gbẹmi ara rẹ yii.
O ke si gbogbo eeyan lati maa fura si ohunkohun to ba n ṣẹlẹ si ọmọnikeji wọn nitori gẹgẹ bi awọn ti gbọ, Treasure ti wa ni ipo ironu tipẹ, ti awọn ti wọn wa layiika rẹ si mọ, ti wọn ko fi to awọn agbalagba ti wọn le tu u ninu leti.
Ọlanrewaju fi kun ọrọ rẹ pe ileewe naa ba awọn obi ọmọdebinrin naa kẹdun, wọn si gbadura pe ki Ọlọrun tu wọn ninu.