O ma ṣe o, awọn agbanipa yinbon pa Babatunde sile-itura kan lọjọ keji ọdun Keresi l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkunrin oniṣowo kan, Babatunde Adeluka, ẹni tawọn eeyan mọ si Tunde Olubasa, lawọn agbebọn ti yinbọn pa nibi to ti n ṣe faaji nileetura Helena, to wa lagbegbe Ijapọ, niluu Akurẹ, lọjọ keji ọdun Keresimesi to kọja.

ALAROYE gbọ pe ilu Akungba Akoko lọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji ọhun ti kuro lọjọ naa lati waa ba wọn ṣayẹyẹ kan niluu Akurẹ.

Ile-itura tiṣẹlẹ yii ti waye ni wọn lọkunrin naa kọkọ gba lọ bo ṣe n wọ igboro Akurẹ lọjọ lati lọọ gba yara silẹ ko too mori le ibi ayẹyẹ to fẹẹ waa ṣe.

Yara to gba sinu otẹẹli naa lo si pada si lẹyin to ti ibi ayẹyẹ to lọ ọhun de.

Ọti ẹlẹridodo to fẹẹ mu ni wọn lo fẹẹ lọọ ra nisalẹ to fi pade awọn gende mẹta nibi ti wọn ti n muti lọwọ.

Ọkan ninu awọn ọkunrin naa ni wọn lo kọkọ sun mọ ọn lati tọrọ iṣana lọwọ rẹ ki wọn le ri nnkan fi mu siga.

Ibi to ti n fọwọ luwọ lati fihan pe oun ti wọn n beere ko fi bẹẹ ye e ni wọn ti da ibọn bo o, awọn agbebọn ọhun si ri i pe ẹmi bọ lara rẹ patapata ki wọn too fi i silẹ sinu agbara ẹjẹ to wa, ti wọn si sa lọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni ọna tawọn agbebọn ọhun gba ṣiṣẹ ibi wọn fihan pe agbanipa ni wọn.

O ni Ọgbẹni Bọlaji Salami to jẹ Kọmisanna awọn ti paṣẹ pe ki ẹkunrẹrẹ iwadii bẹrẹ lẹyẹ-o-ṣọka lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply