O ma ṣe o! Awọn ọmọ iya meji ku sinu ṣalanga

Monisọla Saka

Awọn ọmọ iya meji kan, Musa Abdullahi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ati Rabiu Abdullahi, ẹni ọdun mẹtadinlogun, ni wọn ti ṣe bẹẹ dagbere faye lẹyin ti wọn ko sinu ṣalanga lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lasiko ti wọn n ṣiṣẹ lọwọ, nipinlẹ Kano.

Agbẹnusọ ileeṣẹ panapana ipinlẹ ọhun, Saminu Abdullahi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade to fi lede niluu Kano, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kin-in-ni yii, sọ pe ọkunrin kan to n jẹ Na Musa Abdullahi sir Muhd, lo pe awọn nipe pajawiri pe awọn ọkunrin kan ti wọn n ko ṣalanga ha sinu ẹ lasiko ti wọn n ko o lọwọ.

Ninu ọrọ ẹ lo ti ni, “Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii, ni ileeṣẹ panapana gba ipe ijaya kan ni deede aago mẹsan-an alẹ ku iṣẹju mọkandinlogun, lati ọdọ Ọgbẹni Na Musa Abdullahi sir Muhammad. Alaye to ṣe fun wa ni pe inu ọja Sabon Gari, Layin Abacha, nijọba ibilẹ Fagge, niṣẹlẹ naa ti waye. Nigba tawọn oṣiṣẹ wa debẹ ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ku iṣẹju mẹtala, ni wọn ri i pe awọn ọkunrin meji kan ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa ni wọn n ko ile igbọnsẹ aarin ọja lọwọ tiṣẹlẹ naa fi waye, inu ṣalanga ti wọn n ko lọwọ ni wọn ha si, ti wọn o fi ribi jade mọ”.

Musa Abdullahi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ni wọn lo kọkọ ha sinu ṣalanga, nigba ti aburo ẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ, Abdullahi Rabiu, ẹni ọdun mẹtadinlogun, n gbiyanju lati yọ ọ loun naa yọ sinu ẹ.

Lẹsẹkẹsẹ tawọn oṣiṣẹ panapana debẹ ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ, lasiko ti wọn fi maa ri awọn ọkunrin mejeeji gbe jade, wọn o le mira mọ, nitori ẹ ni wọn ṣe sare gbe wọn digbadigba lọ sile iwosan nla Murtala Mohammed Specialist Hospital ilu Kano, nibẹ lawọn dokita to wa nibẹ ti sọ fun wọn pe awọn mejeeji ti gbẹmii mi.

Wọn ti fa oku wọn le ọga ọlọpaa teṣan Sabon Gari, Abubakar Alhassan, lọwọ, pe ko ba wọn ṣawari awọn mọlẹbi wọn, ki wọn le gbe oku wọn fun wọn.

Ohun ti wọn lo ṣokunfa iku wọn ni ooru to pọ ju ninu ṣalanga naa, ati bi ko ṣe si afẹfẹ ti wọn le mi simu lasiko ti wọn wa ninu ṣalanga ọhun.

Leave a Reply