O ma ṣe o, David Ajiboye, oṣiṣẹ Yinka Ayefẹlẹ ku lojiji

Faith Adebola

A-gbọ-sọgba nu ni ọrọ iku David Ajiboye, ọkan ninu awọn ọlọwọ ọtun akọrin Tungba nni, Ọlayinka Ayefẹlẹ, jẹ fawọn ololufẹ ọkunrin naa atawọn oṣiṣẹ lapapọ.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, la gbọ pe ọmọkunrin naa dakẹ nileewosan alaadani kan niluu Ibadan lẹyin aisan ranpẹ

Akọroyin ni Ọgbẹni Ajiboye ko too darapọ mọ ẹgbẹ olorin Ayefẹlẹ gẹgẹ bii agbẹnusọ rẹ. Yatọ si pe o jẹ agbẹnusọ Ayefẹlẹ, ọmọkunrin yii kan naa lo n mojuto ileeṣẹ redio ti Ayefẹlẹ da silẹ nipinlẹ Ekiti, iyẹn Fresh FM, 106.9 kọlọjọ too de.

Lalẹ ọjọ Aiku yii ni ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa, Samson Akindele, kede lori redio Fresh FM, tilu Ibadan pe ‘Pẹlu ẹdun ọkan ni awọn alaṣẹ ati oṣiṣẹ ileeṣẹ Fresh FM, ati Merry Maker Band fi kede iku ọkan ninu awọn alaamojuto ileeṣẹ redio FM to wa nipinlẹ Ekiti.

‘‘Ọgbẹni Ajiboye ku ni ọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ yii, ni ọsibitu alaadani kan lẹyin aisan ti ko ju ọjọ diẹ lọ.

‘‘Ajiboye jẹ ọkan ninu awọn oṣiṣẹ Merry Maker Band latigba ti wọn ti bẹrẹ. O jẹ ọkan ninu awọn ti wọn ṣatilẹyin fun Yinka Ayefẹlẹ gẹgẹ bii ọrẹ, ko too waa di oṣiṣẹ ileeṣẹ naa latigba ti wọn ti n gbero Fresh FM, ko too waa wa si imuṣẹ.

‘‘Iku ọkan ninu wa yii dun wa, o si ko irẹwẹsi nla ba wa, a fẹ ki ẹ fara da a fun wa niru asiko ta a wa yii.’’

Bẹẹ ni Samson Akindele to gbe ikede naa jade ṣe sọ.

Ko ti i sẹni to ti i le sọ iru iku to pa ọkunrin to gbajumọ daadaa nidii iṣẹ iroyin ati ṣiṣe agbẹnusọ fun Yinka Ayefẹlẹ yii.

Leave a Reply