O ma ṣe o, ‘Dudu Heritage’, ọkọ Bimbọ Ọshin, ku lojiji

Ajalu buruku ni iku iku Ọla Ibironkẹ ti gbogbo eeyan mọ si Dudu Heritage to jẹ ọkọ gbajumọ oṣere ilẹ wa nni, Bimbọ Ọṣhin to ku lojiji.

Ilu oyinbo ni ọkunrin naa n gbe, bo tilẹ jẹ pe o maa n wa si Naijiria daadaa, to si gbajumọ laarin awọn oṣere atawọn olorin.

ALAROYE gbọ pe lojiji ni ọkunrin naa dagbere faye ni alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Ko ti i sẹni to le sọ iru iku to pa ọkunrin naa lasiko ta a n ko iroyin yii jọ.

Awọn olorin ni ọkunrin yii maa n gbe jade, beẹ lo si gbe awọn oṣere diẹ jade pẹlu.

Ọmọ meji, ọkunrin, kan obinrin kan, loun ati Bimbọ Ọṣin bi funra wọn kọlọjọ too de.

Leave a Reply