Faith Adebọla, Eko
Oku eeyan mẹta lawọn apẹja ri yọ jade ninu odo to gba abẹ biriiji Ẹpẹ, nijọba ibilẹ Ẹpẹ, nipinlẹ Eko nigba ti ọkọ akoyanrin kan re bọ latori biriiji ọhun laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ niṣẹlẹ naa waye, wọn ni iwaju mọto naa lawọn eeyan mẹtẹẹta ọhun wa, dirẹba kan atawọn ọkunrin meji mi-in.
Ọgbẹni Nosa Okunbor, Alukoro fun ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, o so pe afaimọ ni ki i ṣe ere asapajude lo ṣokunfa ijamba naa, tori ere buruku lo le mu ki ọkọ to ko iyanrin sẹyin bayii sare kọja kọnkere ti wọn fi ṣe aabo si ẹgbẹ mejeeji biriiji ọhun.
Ọpẹlọpẹ awọn apẹja, awọn omuwẹ atawọn oṣiṣẹ LASEMA ni wọn kọkọ wọ ọkọ tipa naa soke odo, ki wọn too bẹrẹ si i wa oku awọn mẹtẹẹta tọkọ naa da somi ọhun jade.
Okunbor ni awọn ti ko oku awọn to doloogbe naa lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa l’Ẹpẹ, wọn si ti wọ mọto naa kuro nibi to ti le ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ.