O ma ṣe o! Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ṣofo nibi ina to ṣọṣẹ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ina sọ nile alaja mẹfa kan to jẹ ti Alaaja Khadijat Sulaiman, lagbegbe Sabo Line, Isalẹ Maliki, niluu Ilọrin, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ti wọn si n tara aje lakooko ti dukia to to ọkẹ aimọye miliọnu naira si ṣegbe nibi iṣẹlẹ  ọhun.

Ajọ NSCDC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ. Alukoro ajọ naa nipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, sọ pe ina ẹlẹntiriiki to ṣẹju lo ṣokunfa ijamba ina ọhun ati pe ọpẹlọpẹ ajọ panapana to tete de sibi iṣẹlẹ naa nnkan o ba bajẹ ju ohun ti a lero lọ, ti ina naa ko ba tun ran mọ ile to doju kọ ọ. Afọlabi ti parọwa si olugbe ipinlẹ naa lati yago fun gbogbo ohun to le mu ki ijamba ina waye, ki wọn maa pana ẹlẹntiriiki nigbakuugba ti wọn ba fẹẹ jade nile, tabi kuro ninu awọn ṣọọbu wọn gbogbo. Ki wọn si maa kan si ajọ panapana bi iṣẹlẹ ina kan ba n ṣẹlẹ lọwọ.

 

Leave a Reply