O ma ṣe o gomina ipinlẹ Ọyọ telẹ, Alao Akala ti ku o

Jọkẹ Amọri

A-gbọ-sọgba-nu ni iroyin iku gomina to ti jẹ nipinlẹ Ọyọ, Adebayọ Alao Akala jẹ fun gbogbo awọn ti wọn gbọ ọ.

Ọpọ lo tiẹ n jiyan pe ko ri bẹẹ nitori ko si ẹnikẹni to gbọ pe ọkunrin to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ọlọpaa ko tooo di gomina naa n saisan kankan tẹlẹ.

Awọn kan sọ pe gomina tẹlẹ naa wa nibi isinku Soun ilẹ Ogbomọsọ to waja ni nnkan bii oṣu kan sẹyin, bẹẹ lo wa nibi isinku Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji to papoda laipẹ yii.

Wọn ni oju oorun ni ọkunrin oloṣelu pataki yii gba doju iku lọru ọjọ kọkanla mọju ọjọ kejila, oṣu kin-in-ni, ọdun yii

A oo maa fi iroyin nipa iṣẹlẹ naa to yin leti bo ba ṣe n lọ.

Leave a Reply