O ma ṣe o, igbakeji gomina to ṣẹṣẹ fipo silẹ ku lojiji

Surdiq Taofeek, Ado-Ekiti

Lẹyin aisan ranpẹ ti wọn lo ṣe e, Igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti, labẹ iṣejọba Kayọde Fayẹmi to ṣẹṣẹ kogba wọle, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi, ti ku lẹni ọdun mọkandinlọgọrin.

ALAROYE gbọ pe o ti to ọjọ mẹta to ti tẹ baba to ti figba kan jẹ alaga ijọba ibilẹ Ado-Ekiti naa diẹ, ti wọn si gbe e lọ si ọsibitu aladaani kan ti wọn n pe ni Multisystem Hospital, niluu Ado-Ekiti, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ ọhun fun itọju. Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ iru aisan to n ṣe baba naa, o pada ku si ọsibitu ọhun ni oru ọjọ Ẹti mọju aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii.

Laarin ọdun 2018 si 2022 ni ọkunrin to jẹ agbẹjọro, to si tun jẹ oloṣelu naa fi ṣe igbakeji gomina labẹ ọga rẹ, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi.

Ọjọ kẹjọ, oṣu Karun-un, ọdun 1944 ni wọn bi ọkunrin ọmọ bibi ilu Ado Ekiti ọhun.

Wọn ko ti i kede iku ọkunrin naa, ṣugbọn awọn to sun mọ baba naa fidi rẹ mulẹ pe ọkunrin naa ti rewalẹ aṣa.

Leave a Reply