Faith Adebọla
Ijamba ọkọ akẹru pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ takisi kan to waye laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ti sọko ibanujẹ saduugbo Cecilia, nijọba ibilẹ Ẹgbẹda, nipinlẹ Ọyọ, pẹlu bo ṣe mu ẹmi eeyan mẹrin lọ lẹsẹkẹṣẹ.
Ba a ṣe gbọ, wọn niṣe lọkọ akẹru naa rọ lu takisi ọhun nigba tiyẹn fẹẹ bọ soju titi marosẹ Ọyọ si Ifẹ.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe eeyan mẹfa lo wa ninu takisi naa, bo ṣe yiwọ jade si titi lọkọ akẹru yii gba a lati ẹgbẹ, lo ba gba a sinu koto giriwo kan to wa lẹgbẹẹ titi naa, niṣe lọkọ ohun gbokiti loju-ẹsẹ, ni ina nla ba ṣẹ yọ.
Nigba tawọn alaaanu ati awọn aladuugbo yoo fi fa awọn eeyan inu ọkọ takisi naa jade, eeyan mẹrin lo ti doloogbe, nigba tawọn meji wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun lọsibitu ti wọn sare gbe wọn lọ digbadigba.
Wọn lawọn oṣiṣẹ panapana ati awọn ẹṣọ alaabo oju popo, Road Safety, ti de ibi iṣẹlẹ naa, lati dẹrọ ina ọhun, wọn si n dari lilọ bibọ ọkọ, bo tilẹ jẹ pe asidẹnti yii ti fa goo-si-loo lọna marosẹ naa.
Wọn tun ni iṣẹ atunṣe oju-ọna naa wa lara ohun to n fa ọpọ ijamba ọkọ to n waye pẹlu bijọba atawọn agbaṣeṣe ṣe n fi iṣẹ naa falẹ lọtọjọ yii.