O ma ṣe o, inu odo Ọyun ni ileeṣẹ panapana ti gbe oku ọkunrin yii jade

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ko sẹni to le ṣalaye ni pato bi oku gende kan ṣe denu odo Ọyun, nitosi ilu Ijagbo, nipinlẹ Kwara. Ṣadeede ni wọn ri i to le tente sori omi laaarọ Ọjọbọ Tọsidee, ọsẹ yii.

Lai fi akoko ṣofo, ileeṣẹ panapana ni wọn ke pe lati waa gbe oku to ti mu omi yo ọhun jade, ko too di pe o bẹ, ti yoo si fa ajakale arun fun araalu to n mu omi odo naa.

Ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara ṣalaye ninu atẹjade kan pe nnkan bii aago mọkanla ku iṣẹju mẹjọ aarọ ni oṣiṣẹ ajọ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, S.M Adetiba, pe akiyesi awọn si i, tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa si lọọ gbe e jade.

Onimọ-ẹrọ Taiwo to wa niluu Ọffa lo ni awọn fa oku naale lọwọ.

 

Leave a Reply