Angela, iyawo Sẹnetọ Tẹsilim Fọlarin, ku lojiji

Oloye Angela Nwaka  Fọlarin to jẹ iyawo Sẹnetọ to n ṣoju Aarin Gbungbun lbadan nileegbimọ aṣofin agba, Tẹslim Fọlarin, ku lojiji.

Ko ti i sẹni to ti i le fidi iku to pa obinrin to jẹ agbẹjọro naa mulẹ. Ṣugbọn iroyin ta a gbọ lati ẹnu amugbalẹgbẹẹ sẹnetọ naa lori eto iroyin, YSO Ọlaniyi, fidi rẹ mulẹ pe United Kingdom lobinrin naa ku si lẹni ọdun mẹtadinlaaadọta lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

Leave a Reply