Ọlawale Ajao
Nnkan ṣe nileeṣẹ ìṣèwélọ́jọ̀ aarẹ orileede yii ana, iyẹn Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library, laaarọ kutu ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlọgbọn (28), oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, pẹlu bi kinniun ti wọn n sin ninu ọgba ọhun ṣe ki ẹni to n tọju ẹ mọlẹ, to ṣi fa a ya pẹrẹpẹrẹ.
Ọkunrin ọmọ ipinlẹ Bauchi kan to n jẹ Babaji Daule, l’ALAROYE gbọ pe o maa n tọju abo kinniun naa laraarọ, nitori akọṣẹmọṣẹ ni i ṣe nibi ka tọju awọn ẹranko abija.
Ṣugbọn iṣẹ to yan laayo yii naa lo ran an lọ sọrun apapandodo laaarọ kutu ọjọ Satide to kọja yii, nigba ti ẹranko buburu naa deede fo mọ ọn lojiji, to fi eyin da batani si i lara.
Ijamba ọhun naa lo si pada gbẹmi ọkunrin ẹni ọdun marundilogoji (35) naa ni kete ti wọn gba a lẹnu eranko lile yii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, aaye meji ọtọọtọ lo wa ninu ile ti wọn kọ fun kinniun yii, akọkọ ni yara nla ti kinniun naa funra rẹ n gbe, nigba ti ikeji jẹ yara ti wọn maa n ba a gbe ounjẹ rẹ si. Ṣugbọn ki wọn too fi ẹranko ti yoo pa jẹ si ile ounjẹ rẹ yii, wọn ni lati ri i daju pe ile ẹranko abija naa wa ni titi gbọingbọin.
Ṣugbọn nigba ti ọkunrin aṣọ́gbà ẹranko yii gbe ounjẹ tọ kinniun oloola iju lọ, gbayawu ni yara rẹ wa ni ṣiṣi silẹ, nigba ti yoo si fi mọ àṣìṣe rẹ láṣìṣe, jagunlabi ti bẹ gija, o ti fo mọ ọn nigbaaya, o si da eyin de e lọrun gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe fun ẹranko ẹgbẹ ẹ to ba fẹẹ pa jẹ.
“Ariwo Ọgbẹni Daule lawọn ẹṣọ alaabo ileeṣẹ ọhun gbọ ti wọn fi sare jannajanna lọ sibẹ, wọn ba ọkunrin alamoojuto ọgba ẹranko yii
lẹnu kinniun, wọn yinbọn pa ẹranko alagbara naa lati le doola ẹmi ẹlẹgbẹ wọn yii lọwọ ẹranko.
Ibọn ba kinniun, o si ku lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ko pẹ rara ti wọn gba ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji naa lẹnu ẹranko yii loun paapaa da gbogbo ara silẹ, to dero ọrun alakeji.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, sọ pe olori awọn ẹṣọ alaabo ileeṣẹ ọhun lo fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti ni deede aago mẹjọ ku ogun iṣẹju laaarọ ọjọ Satide to gbẹyin oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 ta a wa yii.
Yara ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan ijọba to wa ni Ijaye, iyẹn Ijaye General Hospital, ni wọn gbe oku ọkunrin aṣọ́gbà ẹranko ọhun lọ, ibẹ naa lo ṣi wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.