O ma ṣẹ o, kọmiṣanna ọlọpaa yii ku lojiji

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom, Waheed Adedamọla Ayilara, ti ku o. Aaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ yii, ni kọmiṣanna ọlọpaa naa mi eemi ikẹyin ni ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun ijọba ipinlẹ Eko, Lagos State University Teaching Hospital, (LASUTH)to wa ni Ikẹja, nipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe arun jẹjẹrẹ serọ-setọ to maa n saaba ba awọn ọkunrin ja lo mu ọga ọlọpaa yii, ti wọn si ti n tọju rẹ lati ọjọ diẹ wa.

Iṣẹ abẹ ni wọn ni o lọọ ṣe lọsibitu ijọba yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, ṣugbọn lẹyin wakati diẹ to ṣe e ni wọn ni ẹlẹmi-in gba  a laaarọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, oṣu Kẹjọ yii.

Ọkunrin yii ti figba kan ṣe adele kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko. Lẹyin eyi ni wọn gbe e lọ si ipinlẹ Akwa Ibom, nibi to ti rọpo Ọlatoye Durosinmi. Latigba naa lo si ti wa nipo kọmiṣanna ọhun ko too di pe iku ṣi i lọwọ iṣẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee.

Ọdun 1992 lo ti wọ iṣẹ ọlọpaa lẹyin to ti kawe gboye loriṣiiriṣii ni Fasiti Ibadan ati Eko gẹgẹ bii amofin.

O ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Bẹẹ lo ti figba kan jẹ igbakeji kọmiṣanna ni ẹka to n ri si iwa ọdaran ni Panti, nipinlẹ Eko. Ipo adele ọga ọlọpaa lo wa nipinlẹ Eko ki wọn too gbe e lọ si ipinlẹ Akwa Ibom, gẹgẹ bii kọmiṣanna ọlọpaa kejilelọgbọn nipinlẹ naa. Ipo ọhun lo wa tọlọjọ fi de.

 

Leave a Reply