O ma ṣe o, lasiko ti wọn n ja epo ni mọto yii gbina, o si jona gburugburu 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Iran buruku niran to ṣẹlẹ lọṣan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ariwo, ‘’owo wọgbo’, ni ọpọ eeyan mu bọ’nu, tawọn mi-in si kawọ mọri, latari bi awọn dukia olowo iyebiye ṣe jona, ọkẹ aimọye dukia lo tun ṣofo, ọpọ eeyan si n sa kijokijo ki wọn ma lọọ fara kaaṣa ina buruku to n jo hai hai bii ina ọrun apaadi ọhun. Lasiko ti mọto kan ti wọn ko epo sinu ẹ gbina lojiji niwaju ileepo kan lopopona mọroṣẹ Oko-Olówó, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, to si jona gburugburu.

ALAROYE gbọ lẹnu awọn olugbe agbegbe naa pe sadeede ni mọto to n ja epo ọhun gbina. O ni awọn tiẹ kọkọ ro pe ado oloro lo dun ni, eyi to mu ki gbogbo awọn eeyan ti wọn wa lagbegbe naa ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi wọn. Ṣugbọn ọkan awọn eeyan tun balẹ diẹ nigba ti wọn gbọ pe mọto epo lo gbina.

Ọkunrin to ni mọto ti wọn fi n ko epo ọhun to padanu dukia sibi iṣẹlẹ ina yii, Usman Ajetunmọbi, ṣọ pe lasiko tawọn n ja epo lọwọ lo deede gbina, kọda oun ko mọ ohun to ṣokunfa ina ọhun titi di bi oun ṣe n ṣọrọ yii. O ni gbogbo dukia oun to le ni miliọnu mẹwaa Naira lo ba iṣẹlẹ naa lọ pẹlu bi mọto ọhun ṣe jona raurau. Lara awọn dukia to wa ninu mọto naa to lo jẹ oun logun ju lọ ni maṣinni ti wọn fi n fa omi jade (pumping machine), ti gbogbo rẹ si ba iṣẹlẹ naa lọ pẹlu mọto.

O tẹsiwaju pe mọto toun fi n bọ iyawo atawọn ọmọ naa niyi, oun ko mọ ọna toun yoo gbe e gba bayii, afi ki ijọba ran awọn lọwọ.

Leave a Reply