Ismail Adeẹyọ
Boya owe afago kẹyin aparo, ohun oju n wa loju n ri lọrọ akẹkọọ ileewe poli ipinlẹ Ogun yii ni o, tabi bi wọn ṣe n sọ pe ẹni n wa ifa n wa ofo ni, latari bi wọn ṣe lo fowo ile-iwe rẹ ta tẹtẹ, o tun fi tọrẹ ẹ tiyẹn ko si i lọwọ naa ta tẹtẹ, ni tẹtẹ ba tẹ ẹ patapata, ko jere, ibinu ati ojuti eyi lo si mu ti wọn fi loo ro gbogbo ẹ pin, lo ba diju mọri, o tilẹkun mọ ara ẹ sinu yara, o da kẹmika jẹ, lo ba para ẹ fin-in fin-in.
Samuel Adegoke ni wọn porukọ ọdọmọkunrin to ti le lẹni ogun ọdun ọhun, ileewe gbogboniṣe ijọba apapọ to wa niluu Ilaro, nipinlẹ Ogun, lo ti n kawe, ibẹ si niṣẹlẹ ibanujẹ naa ti ṣẹlẹ.
Ọmọ yii o fi mọ bẹẹ o, lo ba tun ronu ọgbọn toun tun le da, niṣe lo tọ ọrẹ ẹ kan ti wọn jọ n kawe ni poli ohun lọ, lo ba purọ fun un pe inawo pajawiri kan yọju soun, o hun irọ nla kan fun un, o si ni ko fun oun ni nọmba to fi n ṣi akaunti rẹ kan bayii lori ẹrọ ayelujara, niyẹn ba fun un, lo ba tun lọọ fi owo ọrẹ rẹ ọhun ta tẹtẹ. Ṣugbọn kọ bii agbẹ fọkọ kọbe loko lọrọ n bọ si, tẹtẹ naa ko jẹ, niṣe lowo ọrẹ rẹ naa tun ṣe ṣinra, kalokalo gbe gbogbo ẹ mi ni kalo.
Alukoro ileeiwe naa, Ọgbẹni Sọla Abiọla, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin ni l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni wọn pe ọga agba poli naa lori aago lati ileewosan to jẹ ti ti ileewe naa pe ara ọkan lara awọn akẹkọọ wọn ko ya rara, aarẹ naa si lagbara gidi ju eyi ti apa awọn le ka nibẹ lọ.
O ni loju-ẹsẹ lọga-agba ti paṣẹ pe ki wọn maa gbe oloogbe yii lọ si ile-iwosan nla kan to jẹ ti ijọba, niluu Ilaro, nigba ti wọn debẹ ni wọn ri i pe majele, oogun apakokoro ti wọn n pe ni Sniper, ni Samuel da mu. Bo tilẹ jẹ pe awọn dokita gbiyanju gidi lati doola ẹmi ẹ, ko pẹ rara ti akukọ fi kọ lẹyin ọmọkunrin, o jade laye.
Ọkan lara awọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ rẹ to mọ si iṣẹlẹ yii, amọ ti ko fẹẹ darukọ ara ẹ ṣalaye pe awọn alaṣẹ ileewe naa ti ṣofin pe ẹni ti ko ba san owo ile-iwe rẹ ko ni i ṣe idanwo, gbedeke ati sanwo ileewe naa si ti sun mọ, o ni eyi ni oloogbe naa ro lẹyin to fowo ileewe rẹ ati tọrẹ ẹ ta tẹtẹ pe oun at’ọrẹ oun ko ni i lanfaani lati ṣedanwo, lo jẹ ko ṣe nnkan to ṣe yii.
O lawọn ti ranṣẹ pe baba rẹ, awọn si ti ṣalaye fun wọn, amọ baba oloogbe naa ni ki i ṣe igba akọkọ niyi ti Samuel yoo fi owo ile-iwe rẹ ta tẹtẹ, o lo ti hu iru iwa bẹ ri, ṣugbọn toun fun un lowo mi-in lati le lanfaani si idanwo ti wọn fẹẹ ṣe nigba naa.
Olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ ọgba ile-iwe ọhun, Thanni Abdullahi, toun naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe, “o ba ni lọkan jẹ pe ba a ṣe gbiyanju to lati doola ẹmi rẹ, Samuel pada jade laye ni. Ohun to ṣẹlẹ ni pe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni oloogbe yii ati awọn ọrẹ rẹ kan n dari pada bọ lati ibi ti wọn ti lọọ kawe lalẹ, ni baba ọrẹ oloogbe ba fi owo ile-iwe rẹ ranṣẹ si i lọjọ naa pe ko lọọ san an, ko baa le lanfaani ati ṣe idanwo,. Amọ ṣe ni oloogbe yii dọgbọn gba foonu ọrẹ rẹ, lo ba ṣe tiransifa owo ọrẹ rẹ kuro ninu akaunti rẹ, o dari owo naa sibomi-in, o si fowo mejeeji ta tẹtẹ, pẹlu adehun pe oun maa fun un lowo naa pada kilẹ ọjọ keji too ṣu, oun yoo tun san ele fun un lori ẹ.”
“Ọjọ keji ọhun lo gbe majele jẹ, to si para ẹ, nigba ti tẹtẹ naa ko jẹ, towo wọgbo.”