Faith Adebọla
Agbọ-sọgba-nu niroyin iku Muhammed, ọmọ ogbontarigi agbẹjọro to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, Oloogbe Gani Fawẹhinmi.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo ku lẹni aadọta ọdun. A gbọ pe Mohammed sọ pe oun ko le mi daadaa mọ, ni ọlọjọ fi de.
Ọdun 2003 lo ni ijamba mọto to lagbara, eyi to sọ ọ di ẹni ti ko le rin mọ nitori aisan naa ṣakoba fun eegun ẹyin rẹ.
Ṣugbọn pẹlu ipo to wa naa lo fi maa n lọ kaakiri, to si maa n jijangbara lori ọrọ Yoruba ati Naijiria lapapọ.
Iṣẹ agbẹjọro loun naa kọ bii baba rẹ, oun naa si lakọbi Oloogbe Fawẹhinmi lọkunrin.