Adewale Adeoye
Ṣe lọrọ ọhun di bo o lọ o yago fun mi lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, nigba ti mọto awọn ṣọja kan tijọba apapọ orileede yii ni ki wọn maa pese aabo fawọn araalu ọhun ṣeeṣi tẹ oni-Kẹkẹ Marwa kan ati ero meji to gbe sinu rẹ pa patapata. Iṣẹlẹ ọhun waye lagbegbe Garin-Alkali, lẹgbẹẹ ilu Gashua, nijọba ibilẹ Bade, nipinlẹ Yobe. Ṣe lawọn araalu fibinu tu jade lọpọ yanturu, ti wọn si fẹhonu han lori iṣẹlẹ ọhun.
ALAROYE gbọ pe pẹlu pe awọn ṣọja naa pa eeyan mẹta danu lọjọ naa, wọn ko duro rara lati ṣe aajo wọn, ṣe ni wọn n sare lọọ lẹlẹẹlẹ.
Adele alaga ijọba ibilẹ Bade, Ọgbẹni Ibrahim Babangida, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye. Ninu ọrọ tiẹ, olori ilu Bade, Alhaji Abubarkar Umar Suleiman rọ awọn araalu pe ki wọn ṣe suuru lori iṣẹlẹ ọhun.
Ọrọ tutu ti olori ilu naa ba awọn eeyan yii sọ lo jẹ ki wọn so ewe agbejẹ mọ’wọ lọjọ naa.