O ma ṣe o! Eyi ni bi mọto nla meji ṣe fun oṣiṣẹ Road Safety yii pọ titi to fi ku

Monisọla Saka

Iku oro to lagbara lo ṣe bẹẹ gbẹmi Marshal Abiọdun Ajòmọ̀le, ti i ṣe ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ ti wọn n dari ọkọ, ti wọn si n mojuto irọrun awọn onimọto ati ero loju popo, iyẹn Federal Road Safety Commission, (FRSC), lasiko to n ṣayẹwo iwe ọkọ.

Ko sẹni ti yoo wo fidio to gba ori ẹrọ ayelujara kan ọhun, ti aanu abiyamọ ko ni i ṣe e. Aarin pàlàpálá mọto meji lo ha si, wọn ko tiẹ rina ri ori ẹ mọ, nitori bo ṣe ti parẹ mọ aarin ọkọ naa, niṣe ni awọn mọto mejeeji naa fun un dan-in, ti ipa ẹjẹ si han ketekete ni inu aṣọ to wa lọrun ẹ, inu inira yii lo wa titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ahesọ ọrọ to n ja ran-in tẹlẹ ni pe ọkunrin naa fẹẹ fagidi da tirela nla to fun un pa naa duro lati gba nnkan lọwọ ẹ ni, atẹjade ti ileeṣẹ Road Safety fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an yii, fidi ẹ mulẹ pe ẹnu iṣẹ ni Ọgbẹni Ajomọle wa, ọkọ akẹru Cabstar kan to rufin ni ọkunrin naa n da lohun lọwọ ti ọkọ nla Mack kan to gbe kọntena ti wọn n ko ẹru si fi ya bàrà lọọ pa a, gbogbo agbari ọkunrin naa lo si fọnka.

Gẹgẹ bi Ọlabisi Ṣonusi, ti i ṣe alukoro ajọ naa ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita, ẹka ileeṣẹ Road Safety to wa lagbegbe Costain, nipinlẹ Eko, ni oloogbe ti n ṣiṣẹ.

Ọkọ kan ni wọn ni o da duro si ẹgbẹ titi to n yẹ wo lọwọ nigba ti ọkọ nla Mack sọ ijanu rẹ nu, to si lọọ gba a mọ mọto mi-in.

O ni, “Agbegbe Orile Iganmu, nipinlẹ Eko, niṣẹlẹ naa ti waye, DRC MT KPASSU lo ko awọn ikọ kan ṣodi lọjọ Satide, nigba ti iṣẹlẹ buburu ọhun waye ni nnkan bii aago meji ọsan kọja ogun iṣẹju.

Ninu iwadii ta a ṣe la ti ri i pe ọkọ akẹru Toyota Dyna alawọ búlúù, pẹlu nọmba idanimọ AKD 108 XY, ni oloogbe n da lohun lọwọ nigba ti tirela Mack kan ti ko ni nọmba sọ ijanu rẹ nu, to si lọọ rọ lu ọkọ LT Volkswagen mi-in ti wọn n da lohun lọwọ.

“Eleyii lo ta bọọsi Volkswagen ọhun nidii, to si lọọ fi agbara run oloogbe mọ ọkọ tanka kan ti wọn paaki kalẹ si ẹgbẹ ọna, aarin ọkọ mejeeji yii lo run un mọ titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ.

Awọn agbofinro teṣan Orile ni wọn kọkọ lọọ fi ọrọ naa to leti, lẹyin naa ni wọn ranṣẹ pe ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Lagos State Traffic Management Authority, (LASTMA), lati waa kun wọn lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Adari ajọ Road Safety nipinlẹ Eko, Babatunde Farinloye, ba awọn ẹbi oloogbe kẹdun, o si gbadura pe ki Ọlọrun rọ awọn ẹbi ara ati ọrẹ rẹ lọkan.

Wọn ti wọ awọn ọkọ mẹtẹẹta ọhun lọ si agọ ọlọpaa Orile Iganmu, wọn si ti gbe oku ọkunrin naa lọ si ile igbokuupamọsi ni Yaba.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa ti tẹsẹ bọ iwadii ọrọ naa, gbogbo akitiyan ni wọn ni awọn n ṣe lati wa awakọ tirela nla to ṣokunfa ijamba naa ri.

Leave a Reply