Ibdahim Alagunmu, Ilọrin
Agbọ-sọgba-nu ni iku ọkunrin olorin Sẹnwẹlẹ to n ṣe daadaa nidii orin naa, Mukaila Sẹnwẹlẹ, ẹni ti awọn eeyan deede gbọ iku rẹ lojiji. Titi di ba a ṣe n sọ yii ni ọpọ eeyan ki si ti i gbagbọ pe ọmọkùnrin olorin to maa n fi awada, ẹfẹ ati awọn ọrọ aṣa sinu orin rẹ yii ti ku. Ohun to jẹ ko ya ọpọ eeyan lẹnu, ko si jẹ ijọloju fun wọn ni pe ko sẹni to gbọ pe ọmọkùnrin naa n saisan rara, iku rẹ ni wọn kan gbọ lojiji.
ALAROYE gbọ pe ilu Eko ni Mukaila n gbe, ṣugbọn to wa siluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, to jẹ ilu abinibi rẹ laipẹ yii, ti wọn ko si ri apẹẹrẹ aisan kankan lara rẹ titi di alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii, ti wọn gbọ iku rẹ lojiji. A gbọ pe ki iku toopaoju rẹ de yii, lati aarọ kùtùkùtù ọjọ Ẹti, lo ti n dọwẹkẹ pẹlu awọn araale ati awọn araadugbo, iyalẹnu lo si jẹ nigba ti wọn kede iku ẹ lalẹ ọjọ Ẹti yii naa. Eyi lo fi ṣoro fun gbogbo awọn to ri i laaarọ lati gbagbọ
Ọkan lara awọn ẹgbọn rẹ ti a fi orukọ bo laṣiiri lo kede iku oloogbe naa, to si ni ajalu buruku ni iku ọmọkunrin olorin naa jẹ. O ni, ‘’ Ko si apẹẹrẹ aisan kankan lara rẹ, koda, o ni oun maa wa si agboole wa, iyẹn Ile Ẹṣinrogunjo, lalẹ ọjọ Ẹti yẹn, nitori ọdọ awọn ọrẹ rẹ kan lo wa lasiko to wa si Ilọrin yii.
Lojiji la kan gba ipe pajawiri pe ara rẹ n ṣe bakan. Emi ati ẹgbọn mi gbiyanju lati gbe e lọsi ileewosan, ṣugbọn a ko de ọsibitu to fi ku’’.
Tẹ o ba gbagbe, oogun ekute atawọn oogun apakokoro bẹẹ ni ọọkunrin yii fi bẹrẹ aye rẹ, to si maa n kọrin bo ba ti n ta awọn oogun yii lati da awọn eeyan laraya, ati lati fa awọn onibaara si ohun ti o n ta yii. Awọn to gbọ ohun orin rẹ ati ẹbun ti Ọlọrun fun un ni wọn ran an lọwọ, ti ọmọkunrin naa fi di ẹni to n kọrin kiri lode ariya, to si jẹ pe wọn maa n pe e daadaa si pati.
Lara awọn ti Ọlọrun lo fun Mukaila ni ọga awọn onimọto nni, MC Oluọmọ, oun lo ṣugbaa Mukaila to fi di ilu-mọ-ọn-ka. Oriṣịirṣii nnkan to n lọ lawujọ, awọn ẹfẹ, ọrọ ṣajẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ lo fi maa n kọrin rẹ ni Sẹnwẹlẹ, ti awọn eeyan si maa n gbadun rẹ.
Ọkan ninu awọn orin to mu Mukaila to sọ ọ di ilu-mọ-ọn-ka ni orin kan to kọ to fi sọrọ nipa awọn obinrin to maa n fi beresia ko ọyan wọn soke, eyi to pe ni ‘’Ko ni i daa fun eebo to ṣe koste, to ba kuure ko ni i sun un re…
Ọpọ awọn to ti gbọ nipa iku ọmọkunrin yii ni iku rẹ ka lara nitori ẹbun ti Ọlọrun fun un to jẹ ara ọtọ, to fi maa n pa awọn eeyan lẹrin-in.
Ilu Eko ni ọmokunrin naa n gbe, ALAROYE gbọ pe o kan wa siluu Ilọrin fun ariya kan ni. Eto ọhun naa ni ko duro ṣe ti ẹlẹmi-in fi gba a.
Titi di ba a si ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to mọ ohun to ṣokunfa iku ọmọkùnrin to maa n kọ orin Ṣẹnwẹlẹ ọhun.
Lara awọn to ti fidi iku ọkunrin naa mulẹ ni Ọgbẹni Musbau Ẹsinrogunjo, to jẹ oludije sipo alaga kansu nijọba ibilẹ Ìwọ-Oòrùn Ilọrin, ninu ẹgbẹ PDP, níbi eto idibo to kọja yii.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karunlelogun, oṣu Kin-ni-ni, ọdun 2025 yii, ni eto isinku rẹ yoo waye.