O ma ṣe o, nibi ti Toyin ti fẹẹ sọda titi ni mọto ti tẹ ẹ pa l’Ado-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Iroyin ibanujẹ gbaa lo jẹ fawọn eeyan to wa loju ọna Ado-Ekiti si Iworoko-Ekiti lonii, ọjọ Aje, Mọnde, pẹlu bi ọkọ ṣe pa obinrin kan, Toyin Ọmọlẹwa, lasiko to fẹẹ sọda sodikeji.

Iṣẹlẹ naa waye niwaju isọ awọn ẹlẹran to wa lagbegbe naa, awakọ to si wa mọto Volvo s40 Salon to ni nọmba LAGOS KTU 280 DS ọhun gan-an ko mọra lẹyin iṣẹlẹ naa.

Gẹgẹ bi ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣe sọ fun ALAROYE, bi mọto ọhun ṣe gba Toyin lobinrin naa ko ti mira pupọ mọ, bẹẹ ni ẹsẹ ẹ kan ti yọ kuro lara ẹ, mọto ọhun gan-an si gbokiti ko too pada lọọ duro lodikeji.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe bi awọn ọlọpaa ṣe debẹ ni wọn gbe obinrin naa lọ sileewosan, ṣugbọn o jẹ Ọlọrun nipe, wọn si gbe oku ẹ lọ si mọṣuari ileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ekiti (EKSUTH) to wa l’Ado-Ekiti.

O waa ni awakọ mọto to nijamba ọhun wa lọdọ awọn, bẹẹ ni iwadii n lọ lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply