O ma ṣe o, oṣere tiata ilẹ wa ku lojiji

Agbọ-sọgba-nu ni iroyin iku ọkan pataki ninu awọn oṣere ilẹ wa nni, Ọlamilekan Ojo, ti gbogbo eeyan mọ si Gbatami.

Aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla yii, ni iroyin iku rẹ deede gba ori ẹrọ ayelujara. Gbogbo awọn ti wọn gbọ nipa iku to pa ọkunrin yii ni wọn n sọ pe ko jẹ jẹ bẹẹ, o ba ẹni gbogbo lojiji.

Ṣe ọpọ eeyan ni ko mọ pe oṣere to maa n kopa tawọn eeyan fẹran daadaa ninu ere naa ti wa ni idubulẹ aisan, o to ọjọ mẹta. Iwadii ALAROYE fi han pe aisan jẹjẹrẹ ẹdọ fooro (lung cancer) ni wọn lo n ba ọkunrin naa finra, to si ti n gbatọju lọjọ to pẹ diẹ.

ALAROYE gbọ pe ọkunrin naa ti kọkọ figba kan lọ siluu oyinbo lati lọọ tọju aisan to n ṣee yii, ko too tun pada wa si Naijiria. Ṣugbọn aisan nikan leeyan ri wo, ko sẹni to ri ti ọlọjọ ṣe. Ọjọbọ lo pada mi imi ikẹyin.

O ṣe diẹ ti ọkunrin yii ti wa lagbo tiata, koda, o ti le logun ọdun to ti n ṣere, bakan naa lo n gbe fiimu jade. Lara awọn fiimu to ṣe jade ki ọlọjọ too de ni: ‘Ọjọ Oro’, ‘Emi nire kan’, ‘Wọnyọsi’ ‘Ṣalaye’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lara awọn to ti daro iku ọkunrin oṣere yii ni Ṣeyi Ẹdun, niṣe lo kọ ọ si ori Instagraamu rẹ pe ‘Sun un re o, ọga mi, o ṣoro fun mi lati gba eleyii gbọ’.

Bakan naa ni oṣere ilẹ wa to fi orileede Amẹrika ṣe ibugbe nni naa pariwo, to ni, ‘Ọmọ, iroyin yii pin ọkan mi si meji ni, ṣe o n ṣe aisan tẹlẹ ni?

Ọkan ninu awọn ololufẹ rẹ kan, tun kọ ọ pe ‘O ṣoro fun mi lati gbagbọ pe pe Gbatami ti ku. Gbatami gbogbo Gbagada, a maa ṣafẹẹri rẹ o, maa sinmi ninu Oluwa’.

Ẹni kan to pe ara rẹ ni ayọmitunde sọ pe ‘Mo ri i ni ọfiisi ti wọn ti n gba pasipọọtu ni Ikoyi ni oṣu diẹ sẹyin, o jẹ eeyan jẹẹjẹ to si ko gbogbo eeyan mọra.

Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n daro ọkunrin oṣere ti wọn n pe ni Gbatami yii, ti wọn si n gbadura pe ki Ọlọrun rọ awọn ẹbi rẹ loju.

Leave a Reply