O ma ṣe o, ọkọ ajagbe tẹ obinrin to n lọ jẹẹjẹ ẹ pa l’Ekoo

Faith Adebọla

Obinrin kan tẹnikẹni ko ti i mọ orukọ ẹ titi di ba a ṣe n sọ yii lo ti kagbako iku airotẹlẹ latari ijamba ọkọ tanka kan to waye ni agbegbe Mile 2, nitosi Nigeria Army Signal Barracks, ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, lọna marosẹ Apapa si Oshodi, nipinlẹ Eko.

Niṣe ni tirela ọhun ti epo bẹntiroo kun inu rẹ temutemu ṣubu yakata, to si dabuu ọna marosẹ ọhun, bẹẹ lobinrin agbalagba naa wa labẹ taya rẹ, aṣọ ankara buluu lo wọ, o ti ku fin-in fin-in.

Alukoro fun Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, (LASEMA) Ọgbẹni Nosa Igiebor, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o lawọn oṣiṣẹ ajọ naa pẹlu irinṣẹ to le wọ mọto ti wa nibi ijamba naa, mọto panapana si ti debẹ pẹlu, nitori ewu ijamba ina to le ṣẹlẹ.

Nosa ni o ṣee ṣe ko jẹ ere asapajude lo ṣokunfa iṣẹlẹ yii, paapaa bi ọkọ naa ṣe ti loodu epo ẹgbẹrun lọna marundinlọgọta lita, ti eyi si le maa fi i sọtun-un sosi. O fi kun un pe afaimọ ko ma jẹ pe niṣe lọkọ naa lọọ subu lu obinrin to n rin lọ jẹẹjẹ tirẹ mọlẹ.

O jọ pe dirẹba ọkọ ọhun ti sa lọ, tori ko sẹnikan to kofiri rẹ, ṣugbọn iṣẹ ti n lọ lati yọ oku obinrin naa labẹ ọkọ ọhun.

Nosa si ti ṣeleri pe awọn yoo wadii ohun to ṣokunfa ijamba yii.

Leave a Reply