Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Iṣẹlẹ ibanujẹ gbaa lo ṣẹlẹ niluu Ikẹrẹ-Ekiti lopin ọsẹ to kọja nigba ti ọkọ ajagbe kan pa awọn ọmọọya meji, Ojo Hezekiah Abidemi ati Ojo Ayọmide.
Tẹgbọn-taburo naa la gbọ pe wọn jẹ ọmọleewe giga University of Nigeria, Nsukka, ẹka tilu Ikẹrẹ-Ekiti nigba aye wọn, wọn si n ṣeto lati lọ siluu Akurẹ, nipinlẹ ondo, lati ri awọn obi wọn nigba tiṣẹlẹ naa waye.
Awakọ ọkọ ajagbe naa kọkọ sa lọ kọwọ too tẹ ẹ, o si ti n ṣalaye ara ẹ fawọn ọlọpaa, bẹẹ ni oku awọn oloogbe wa ni mọṣuari di akoko yii.