Ọlawale Ajao, Ibadan
Bi wọn ba n sọ pe iku ko eeyan nifa, ọrọ iku ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27), kan lo ṣapejuwe iru iṣẹlẹ bẹẹ lopin ọsẹ to kọja pẹlu bo ṣe jẹ pe oun funra ẹ lo fẹsẹ ara ẹ rin lọ sidii kanga, funra ẹ naa lo si ko sinu omi naa titi ti iku fi wọle tọ ọ ninu kanga naa, to si pa a nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja.
Ọmọkunrin ọhun, to jẹ kọndọ ẹyin ọkọ ẹru nla kan lo lọ sidii kanga naa lati pọn omi ti wọn yoo rọ sinu radietọ ọkọ wọn nigba ti mọto naa bajẹ laduugbo ti wọn n pe ni Alaja, nijọba ibilẹ Akinyẹle, niluu Ibadan, ṣugbọn ti igbesẹ ọhun ja siku fun un.
Gẹgẹ bi olugbe adugbo ọhun kan to wa nitosi lasiko ti iṣẹlẹ naa waye ṣe sọ, ‘mo ri ọmọkunrin yẹn nirọlẹ Satide yẹn. Mo ro pe mọto wọn lo bajẹ, oun lo si ni lati lọọ pọn omi ti wọn maa rọ sinu radietọ ọkọ yẹn gẹgẹ bii ọmọ ẹyin ọkọ.
“Lẹyin to ti wa ifami ti ko ri, lo wa ike ifalọwọ kan, to wa okun kan so mọ ọn, to si ju ike naa sinu kanga lati fi fa omi jade.
Ṣugbọn ko ti i fa omi akọkọ doke ti okun to so mọ ike naa fi ja. Nigba ti ko ri nnkan to fi maa yọ ifami rẹ jade lo ko sinu kanga lati yọ ifami naa, ṣugbọn ti oun funra rẹ ko le jade mọ.
“Ko sẹni to mọgba ti ọmọkunrin yii ko sinu kanga. Ṣugbọn nigba ti ọga ẹ reti ẹ ti ko ri i lo bẹrẹ si i wa a kiri. Bata rẹ to ri nidii kanga lo fi mọ pe o ni lati jẹ pe inu kanga yẹn lo ko si. Nigba yẹn lo figbe bọnu, ti gbogbo araadugbo si pe jọ sibẹ.
“Ṣugbọn ko sẹni to lori laya lati ko sinu ọhun lati yọ ọmọkunrin naa, afigba ti awọn oṣiṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ de lati yọ ọ, ṣugbọn oku ẹ ni wọn ri yọ jade”.
ALAROYE gbọ pe ṣaaju iṣẹlẹ yii, paanu lasan ni wọn fi maa n de kanga naa, ti wọn si maa n fi okuta le paanu ọhun lori”.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọwale Williams, sọ pe wọn ti ti kanga naa pa lati dena ijanba to tun ṣee ṣe ko ṣe ẹlomi-in latipasẹ kanga naa titi ti wọn yoo fi ṣe ideri gidi si i lori.