Ọlawale Ajao, Ibadan
Inu ọfọ nidile Oritokẹ, alaga ijọba ibilẹ Onidagbasoke Aarin-Gbungbun Ogbomọṣọ wa bayii, pẹlu bi wọn ṣe padanu ọmọkunrin wọn kan sinu ijamba ọkọ.
Ọmọkunrin naa, Sẹfiu Arẹmu, lo padanu ẹmi ẹ ninu ijamba ọkọ to waye lọna Ogbomọṣọ siluu Ilọrin nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindilogun, oṣu Keje, ọdun 2022 yii.
Ṣefiu to padanu ẹmi ẹ sinu ijamba yii lo jẹ ọmọ bibi inu Ọnarebu Adijat Oritokẹ ti i ṣe alaga ijọba ibilẹ Onidagbasoke Aarin-Gbungbun Ogbomọṣọ.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ ẹgbọn iya ẹ ti wọn lọọ ṣe niluu Babalomọ, nipinlẹ Kwara, oun pẹlu tọkọ-tiyawo tuntun pẹlu afẹsọna oun funra rẹ ni wọn wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ kan naa to jẹ ti iya ẹ ti i ṣe alaga yii.
Bo ṣe ku diẹ ki wọn wọlu Ogbomọṣọ lọkọ naa deede padanu ijanu ẹ, to si gbokiti leralera ko too duro.
Okiti ti ọkọ yii n ta lo sọ Arẹmu danu lati oju ferese jade ninu mọto. Tipatipa ni wọn fi fa ọmọ alaga kansu yii jade ninu mọto, o ti ku patapata. Gbogbo ori ẹ lo kun fun ẹjẹ, nibi to ti n fori gba nnkan lasiko laasigbo naa.
ALAROYE gbọ pe Ọnarebu Oritokẹti kuro niluu Babalomọ ti wọn ti lọọ ṣegbeyawo naa, ilu Ogbomọṣọ lo wa ti wọn ti gbe oku ọmọ ẹ lọọ ba a.
Ọgbẹni Azeez, ọkan ninu awọn ọrẹ Arẹmu, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Don H Jahbless, sọ pe “kayeefi ni iku ẹ jẹ fun mi, nitori titi di ọgbọn iṣẹju ṣaaju iku ẹ lo ṣi n fi iroyin ranṣẹ nipa gbogbo bi nnkan ṣe n lọ nipa eto idibo ipinlẹ Ọṣun ranṣẹ sawọn eeyan lori ẹrọ ayelujara, nitori ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP gidi lo jẹ.
“Lojiji la o kan deede gburoo rẹ mọ lori ẹrọ ayelujara, afi bi mo ṣe deede ri i ti wọn tufọ rẹ lori fesibuuku pe “sun ire o”.