O ma ṣe o, ọmọ ọdun mẹrin ja si ṣalanga lasiko ti wọn n gba bọọlu l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Inu ipayinkeke ati ibanujẹ ni obi ọmọ ọdun mẹrin kan wa bayii pẹlu bi wọn ṣe sadeede ba oku rẹ ninu ṣalanga kan ni adugbo Aseparisi, lagbegbe Adehun, niluu Ado-Ekiti.

Gẹgẹ bi awọn araadugbo naa to ba ALAROYE sọrọ ṣe sọ, wọn ni ọmọde yii atawọn ẹgbẹ rẹ kan ni wọn jọ n gba bọọlu nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ṣugbọn lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn ti n gba bọọlu ọhun ni bọọlu wọn yii ha si aarin igi kan ti wọn gbin si ẹgbẹ ṣalanga yii.

Ọmọdekunrin to ti doloogbe yii lo gbiyanju lati mu bọọlu to ha saarin igi naa, ṣugbọn lojiji lo sadeede ja sinu ṣalanga naa.

Bo ṣe ja sinu ṣalanga yii ni awọn iyooku rẹ bẹrẹ si i pariwo titi ti awọn araadugbo naa fi jade. Wọn gbiyanju lati yọ oku rẹ kuro, ṣugbọn ki wọn too gbe e jade ni ọmọ naa ti dagbere faye.

Iṣẹlẹ yii da jinnijinni silẹ laarin awọn araadugbo naa. Lẹyin ti wọn gbe oku ọmọde yii jade ni wọn gbe e lọ si ile igbokuu-pamọ si kan to jẹ tijọba niluu Ado-Ekiti.

Lara awọn olubanikẹdun to ba ALAROYE sọrọ lori iku ọmọdekunrin yii di ẹbi iku ọmọ yii ru awọn ọmọ yii, o ni wọn ko mojuto ọmọ naa to ni.

Wọn waa rọ awọn obi ki wọn maa mojuto awọn ọmọ wọn, bẹẹ ni wọn gba awọn to ba n gbẹ ṣalanga niyanju lati maa gbẹ ẹ daadaa.

Alukoro awọn ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe wọn ti tọju oku ọmọ naa, iwadii si ti bẹrẹ lori ọrọ naa.

 

Leave a Reply