O ma ṣe o, ọmọ olorin fuji kan ku lojiji

Aderohunmu Kazeem

Ninu ibanujẹ nla ni gbajumọ olorin fuji nni, Kareem Ayinde Ọsọba, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Kabiesi Olomide wa bayii, iku ojiji lo pa ọmọ ẹ obinrin, Rachael Ọlamide Ayọka Ọsọba, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja.

Lori ẹrọ ayelujara Facebook ẹ, Kareem Ayinde Kabiesi, lo gbe ọrọ ọhun si, nibi tawọn eeyan ti n ba a kẹdun gidigidi.

Ohun ti ọkunrin naa kọ nipa ọmọ ẹ yii, Rachael Ọlamide Ayọka Ọsọba ko ṣai mu ọpọ eeyan ba a kẹdun gidigidi, ti wọn si n tọrọ wi pe ki Ọlọrun foriji ọmọ naa, ko si ba a da awọn yooku si.

Ohun ti Kabiesi Olomide kọ ree, “Rachael Ọlamide Ayọka Ọsọba, ala rẹ lati jẹ ojulowo ọmọ orilẹ-ede Nigeria yii ninu iṣẹ ọlọpaa ko le pada wa si imuṣẹ mọ.

“Lati le di ọlọpaa to yaranti lọjọ iwaju lo mu ẹ darapọ mọ ileewe Police Force Secondary School, n’Igbo-Ọra, nipinlẹ Ọyọ, nibi to o ti ṣẹṣẹ pari ipele akọkọ ẹkọ girama laipẹ yii. Ọjọ kẹrin, oṣu yii, naa lo pari idanwo rẹ, ti o si pada waa ba wa nile.

“Nigba to di Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii. lọwọ aarọ lo sọ pe ara n ro ẹ, loju ẹsẹ naa la si gbe ẹ lọ si ileewosan ijọba. Nigba to di Furaidee, ọjọ Ẹti, to tẹle e, funra ẹ naa lo ji, o gbadura gẹgẹ bii iṣe rẹ, bẹẹ lo bu omi sara, ti o si tun jẹ awọn eeso ti a ni nile, ṣugbọn lojiji ni gbogbo nnkan daru, ti a si sare gbe ẹ lọ si ileewosan Jẹnẹra n’Ifakọ Ijaye, nibi ti o ti mi eemi ikẹyin.

“Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ ileewosan naa gbiyanju agbara wọn, sibẹ, a fẹ ọ ni o, ṣugbọn Ọlọrun lo fẹ ọ ju, ki Ọlọrun ba mi tẹ ọ safẹfẹ rere, nigba ti a oo tun pade lọjọ ajinde…O daarọ, Ọla mi.”

Ohun ti gbajumọ olorin fuji yii, to tun jẹ ọkan pataki ninu awọn oloye ẹgbẹ PMAN, gbe sori Facebook ẹ ree, ti awọn eeyan bẹrẹ si ki i, ti wọn si n ba a kẹdun gidigidi.

Leave a Reply