Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọkan ninu awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ilẹ wa tẹlẹ, Sẹnetọ Rafiu Ibrahim, la gbọ pe o ku lojiji l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lẹni ọdun mẹtadinlọgọta (57).
Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe aisan ranpẹ lo ṣe ọkunrin naa. Ojiji ni wọn ni ọkan rẹ daṣẹ silẹ, to si ku sileewosan kan niluu Abuja.
Sẹnetọ Rafiu Ibrahim jẹ ọmọ bibi ilu Òjòkú, ni Guusu ipinlẹ Kwara, o si ti figba kan jẹ ọkan lara awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja.
Owuyẹ kan sọ pe latibẹrẹ ọdun to kọja ni ara agba oloṣelu yii ko ya, ṣugbọn ti wọn ko pariwo rẹ sita, ko too waa di pe ọrọ naa yiwọ, ti aisan naa si pada mu ẹmi ọkunrin oloṣelu naa lọ.
O dije dupo ṣẹnatọ fun saa keji lọdun 2023, ṣugbọn o fidi-rẹmi, ti ipo naa si ja mọ ojugba rẹ, Lọla Ashiru, lọwọ.