Ọlawale Ajao, Ibadan
Awakọ tanka epo bẹtiroolu kan ti j’Ọlọrun nipe ninu ijanba ọkọ to waye lori biriiji Soka, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. Niṣe ni ọkọ nla ọhun gbokiti sinu omi Soka lati ori biriiji odo naa.
Gẹgẹ b’awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe sọ, ṣadeede lọkọ ọhun to n ti ọna Iwo Road, n’Ibadan, lọ sọna Eko, ya bara kuro loju titi, to si re sinu odo jínjìn naa.
Awọn eeyan sare sọ kalẹ sinu odo ọhun lati ran awọn to wa ninu mọto naa lọwọ, nigba naa ni wọn ri i pe awakọ yii nikan ṣoṣo lo wa ninu mọto, loju ẹsẹ lo si ti ku.
Awọn to sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe bireeki ọkọ ọhun to daṣẹ silẹ lojiji lo ṣee ṣe ko ṣokunfa ijanba naa. Ṣugbọn Ọgbẹni Shehu Umar, alamoojuto ẹka to n ri si ajalu buburu fun ajọ alaabo ilu ta a mọ si Sifu Difẹnsi nipinlẹ Ọyọ sọ pe o le jẹ oorun to n kun awakọ naa nitori àárẹ̀ to ti mu un latari ọna jinjin to ti n bọ lo mu ki ọwọ ọkọ naa ya bara sinu odo, ti ko si ri ara dù pada mọ titi to fi bọ sinu omi.
O ni ni kete ti ijanba ọhun ti waye ni wọn ti tẹ ileeṣẹ oun laago, tawọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi si sare lọ sibẹ lati doola ẹmi awọn eeyan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awa atawọn panapana la jọ wa nibẹ lati doola ẹmi awọn eeyan, paapaa lati dena ki awọn eeyan ma baa maa ji bẹtiroolu to n ṣẹ jade latinu tanka epo yẹn bu, ki iyẹn naa ma tun lọọ fa ijanba to ṣee ṣe ko tun la ẹmi lọ”.
Ileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Adeọyọ ni wọn gbe oku awakọ epo naa pamọ si gẹgẹ bi ọga awọn Sifu Difẹnsi yii ṣe fidi ẹ mulẹ.