Florence Babaṣọla
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni iku ọmọkunrin agẹri kan (barber), Tayọ Ọlatunji, ṣi n ṣe awọn eeyan agbegbe Oke-Opo, niluu Ileṣa, ni kayeefi.
Aarọ ọjọ Aiku, Sannde, to kọja, ni wọn sọ pe ọkunrin ẹni ọdun marunlelogoji naa dedde jade nile lai dagbere ibi kankan funyawo rẹ to wa ninu oyun.
Nigba to yẹ ko pada wọle ti wọn ko gburoo rẹ ni wọn fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, bayii ni wọn bẹrẹ si i wa a.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn deede ri oku rẹ nibi to ti n mi dirodiro lori igi nitosi odo kan ninu adugbo naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
A gbọ pe lẹyin ti awọn alawo ṣe awọn etutu to yẹ nibẹ ni wọn ge okun to fi rọ mọ igi.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn mọlẹbi rẹ ti kọkọ n wa a bẹrẹ lati ọjọ Aiku, ti wọn si fi to awọn ọlọpaa leti.
Ọpalọla ṣalaye pe ko si ẹnikankan to le sọ ni pato ohun to fa a ti ọkunrin naa fi pokunso. O ni iwadii ti bẹrẹ lati ri ojutuu ọrọ naa.