O ma ṣe o, wọn ni Ọlabọde luyawo ẹ pa toyuntoyun l’Akurẹ

Awọn ọlọpaa ti mu ọkunrin kan ti wọn n pe ni Oluwaṣeun Ọlabọde o. Ẹsun pe o lu iyawo rẹ pa toyuntoyun ni wọn fi kan an. Ile-ẹjo majisireeti kan ni wọn gbe e lọ niluu Akurẹ, nibi ti wọn ti sọ fadajọ pe niṣe ni Ọlabọde lu Blessing, iyawo ẹ to wa ninu oyun, pa.

Olupẹjọ ijọba, Uloh Goodluck, sọ niwaju ile-ẹjọ pe Ọlabọde fi gbogbo agbara gba nnkan mọyawo ẹ ninu ni, nibẹ ni Blessing si ti digbo lulẹ, lo ba ku. O da a labaa fun ile-ẹjọ pe ki wọn ma gba beeli ọdaran naa, nitori ẹsun apaayan lawọn fi kan an, ẹsun to si lodi si ofin ipinlẹ Ondo patapata gbaa ni.

Adajọ Aladejana gba aba naa wọle, o ni ki wọn fi Ọlabọde pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun yii ti wọn yoo bẹrẹ si i gbọ ẹjọ naa gan-an.

Leave a Reply