Adajọ ni ki wọn yẹgi fun Jẹgẹdẹ titi ti ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ  

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti 

Ile-ẹjọ giga kan to wa nipinlẹ Ekiti, niluu Ado-Ekiti, ti paṣẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe ki wọn lọọ yẹgi fun ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Ṣọla Jẹgẹdẹ, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ, latari pe o jẹbi ẹsun ole jija ati ifipa-bani-lo-pọ.

Ninu iwe ẹsun ti wọn ka ṣaaju ki idajọ too waye, wọn ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2015, ni aduugbo Ọda-Pọnna, niluu Omuo-Ekiti, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ekiti, ni Jẹgẹdẹ ti huwa ọdaran ọhun.

Wọn ni niṣe lo dihamọra pẹlu awọn ohun ija oloro bii ibọn, ọbẹ, aake ati ponpo, to si lọọ digun ja tọkọ-tiyawo kan, Ilesanmi Ibukun ati Ilesanmi Ṣeun lole, o gba foonu alagbeeka wọn ati owo iyebiye lowo awọn mejeji.

Wọn lawọn ẹsun wọnyi lodi sofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ekiti tọdun 2012.

Onidaajọ Oluwatoyin Abọdunde to gbọ ẹjọ naa sọ pe oun tu ọdaran naa silẹ lori ẹsun kẹrin ati ikarun-un, o lawọn ẹsun naa ko ni ẹri to daniloju, ati pe ile-ẹjọ ko le sọ afurasi ọdaran sẹwọn lori ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ.

Abọdunde ni lori awọn ẹsun meji to tan mọ idigunjale, Agbefọba, Inspẹkitọ Ọmọbọla Oyewọle, to ṣoju fun ijọba gẹgẹ bii olupẹjọ ti pe ẹlẹrii meje ọtọọtọ, to si tun ko awọn ẹri silẹ lati gbe ọrọ rẹ lẹsẹ pe loootọ ni ọdaran naa huwa idigunjale.

O ni ọdaran naa ati agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Adedayọ Adewumi, ko pe ẹlẹrii kankan.

Latari eyi, adajọ ni ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ yii ti foju han pe adigunjale pọmbele lọkunrin naa, tori naa ki wọn lọọ gba ẹmi lẹnu ẹ.

Leave a Reply