O ma ṣe o, agbara ojo gbe akẹkọọ kan lọ n’Ikarẹ Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan ninu awọn akẹkọọ ileewe girama awọn obinrin Mount Carmel, to wa niluu Ikarẹ Akoko, Motunrayọ John, ni wọn lagbara ojo gbe lọ lọsan-an ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ibi tiṣẹlẹ yii ti waye ko fi bẹẹ jinna sibi omi nla kan ti wọn n pe ni Odo Dada, eyi to wa lagbegbe Ṣemusemu, niluu Ikarẹ.

Ọmọbinrin to si wa ni kilaasi kẹta akọkọ ni wọn ni omi ṣeesi gbe lọ pẹlu bo ṣe n ṣere loju agbara ninu ojo nla kan to rọ lọjọ naa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun wa, ọga ọlọpaa tesan Ikarẹ, Ọgbẹni Ọlatujoye Akinwande, ni ọga agba ile-iwe Mount Carmel, Abilekọ Ajọkẹ Asiwaju, ti waa fi ọrọ naa to awọn leti lọgan tiṣẹlẹ ọhun waye.
O ni ni kete ti awọn ti gbọ nipa ohun to sẹlẹ lawọn ti bẹrẹ igbesẹ wiwa ọmọ naa, ṣugbọn ti gbogbo akitiyan awọn ko ti i so eeso rere lasiko to n ba wa sọrọ.

Lẹyin eyi lo gba awọn obi nimọran lati maa mojuto ọmọ wọn daadaa, ki wọn si ri i daju pe wọn ko ṣere loju agbara lasiko ojo.

Ni ibamu pẹlu ohun ta a fidi rẹ mulẹ lati ẹnu awọn eeyan ilu Ikarẹ Akoko, wọn ni eeyan bii mẹta ni Omi Dada to wa nitosi ibi iṣẹlẹ naa ti gbe lọ lai ti i pẹ rara.

Ko ti i ju bii ọdun meji sẹyin ti agbara ojo wọnu ile gbe ọmọbinrin akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin to wa l’Akungba Akoko lọ, ti ko si sẹni to ṣalabaapade oku rẹ lati igba naa titi di ba a ti n sọ yii.

Leave a Reply