O ma ṣe o, akẹkọọ UNIOSUN para ẹ, majele lo gbe jẹ

Florence Babasola, Oṣogbo

Akẹkọọ kan to wa nipele akọkọ ni ẹka ileewe UNIOSUN to wa niluu Ikire, Juba Babatunde Philips, lo ti gbẹmi ara rẹ bayii.

Oogun ti wọn fi n pa kokoro (snipper), la gbọ pe Babatunde, ẹni to wa ni ẹka ti wọn ti n kọ nipa ere itage, Theatre Art. lawọn ọrẹ rẹ ba oku ẹ ninu yara rẹ nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọsẹ yii.

Gẹgẹ bi iwadii ṣe fi han oniruuru ọrọ nipa igbẹmi ara ẹni ni ọmọdekunrin naa ti n kọ sori ikanni ayelujara rẹ lẹnu lọọlọ yii.

Agbẹnusọ ileewe UNIOSUN, Adesọji Ademọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ṣalaye pe ko ti i si ẹnikẹni to le sọ ni pato nnkan to mu ki oloogbe gbe igbesẹ naa.

Bakan naa ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe olori ẹṣọ alaabo ileewe naa, Akintibubọ Rahman, lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, wọn si ba agolo oogun to lo ọhun lẹgbẹẹ rẹ.

Ọpalọla ni wọn ti gbe oku rẹ lọ sile igbokuu-si ti ileewosan Catholic Hospital, Oluyoro, Apomu fun ayẹwo to peye.

Leave a Reply