O ma ṣe o, arun Korona pa eeyan mẹta l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ibẹru-bojo ti gba ọkan awọn eeyan nipinlẹ Ekiti pelu bi Kọmiṣanna fun eto ilera nipinlẹ naa, Dokita Oyebanji Filani, ṣe kede pe arun Korona ti ran eeyan mẹta sọrun ọsan gangan nipinle naa laarin ọsẹ meji.

Meji lara awọn to ku naa ni wọn jẹ ẹni ọdun marunlelaaadọta, nigba ti ẹn kan to ku jẹ ẹni ọdun marunlelogojieyan meta naa ni won je eni odun marunlelaadota odun ti enikan lara won si je eni odun marunlelogoji, ti awọn meji lara wọn si jẹ mọlẹbi kan naa.

Filani fi kun un pe ipinlẹ naa ti gba abẹrẹ ajẹsara ti ko din ni ẹgbẹrun lọna mejilelaaadọta lati ọdọ ijọba apapọ, eyi ti wọn yoo fun aọn olugbe ipinlẹ naa lati dena bi awọn eeyan naa ṣe n ko arun Koronafairọsi.

Ijọba ti waa ṣekilọ awọn ti wọn ba ti gba abala akọkọ abẹrẹ naa ti wọn pe ni (Astrazenca Vaccines) ko gbọdọ waa gba abẹrẹ naa mọ.

Kọmiṣanna ni nigba ti aọn eleto ilera n lọ kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni ipinlẹ naa, ẹgbẹrun mẹta eeyan ni wọn ti ṣe ayẹwo fun, ti eeyan bii igba meji si ti fara ko aisan naa, nigba ti aadọrin eeyan ti ri iwosan gba lẹyin ti wọn fara ko aisan naa.

 

Leave a Reply