O ma ṣe o, awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi meji ku sinu ijamba ọkọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

Meji ninu awọn oṣiṣẹ ajọ Sifu Difẹnsi ẹka tipinlẹ Ondo, ni wọn ku, ti ẹni kan si tun fara pa ninu ijamba ọkọ kan to waye lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ oṣu yii.

Awakọ bọọsi elero meje to gbe awọn ẹsọ alaabo ọhun ni wọn lo padanu ijanu ọkọ rẹ loju ọna marosẹ Ọrẹ si Ondo lasiko ti wọn n bọ lati ibi ariya isinku kan ti wọn lọọ ṣe l’Okitipupa.

Wọn ní bi ọkọ bọọsi naa ti wọgbo mọ awakọ yii lọwọ lo ti takiti wọ inu koto nla kan to wa lẹgbẹẹ ọna, leyii to ṣokunfa iku meji ninu awọn eeyaan ọhun loju ẹsẹ, ti ẹni kan ninu wọn si tun farapa yannayanna.

Wọn ti gbe ẹni to ṣeṣe ninu wọn lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun to wa niluu Ondo, nibi to ti n gba itọju lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ.

Alukoro ajọ naa nipinlẹ Ondo, Olufẹmi Ọmọle, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun akọroyin wa, o ni ọga agba patapata fun ajọ ọhun nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Okoro Eweka, naa ti ba ẹbi awọn to ku ọhun kẹdun.

Leave a Reply